Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joṣ 10:4-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. Ẹ gòke tọ̀ mi wá, ki ẹ si ràn mi lọwọ, ki awa ki o le kọlù Gibeoni: nitoriti o bá Joṣua ati awọn ọmọ Israeli ṣọrẹ.

5. Awọn ọba Amori mararun, ọba Jerusalemu, ọba Hebroni, ọba Jarmutu, ọba Lakiṣi, ati ọba Egloni, kó ara wọn jọ, nwọn si gòke, awọn ati gbogbo ogun wọn, nwọn si dótì Gibeoni, nwọn si fi ìja fun u.

6. Awọn ọkunrin Gibeoni si ranṣẹ si Joṣua ni ibudó ni Gilgali, wipe, Má ṣe fà ọwọ́ rẹ sẹhin kuro lọdọ awọn iranṣẹ rẹ; gòke tọ̀ wa wá kánkán, ki o si gbà wa, ki o si ràn wa lọwọ: nitoriti gbogbo awọn ọba Amori ti ngbé ori òke kójọ pọ̀ si wa.

7. Bẹ̃ni Joṣua gòke lati Gilgali lọ, on ati gbogbo awọn ọmọ-ogun pẹlu rẹ̀, ati gbogbo awọn alagbara akọni.

8. OLUWA si wi fun Joṣua pe, Má ṣe bẹ̀ru wọn: nitoriti mo ti fi wọn lé ọ lọwọ; ki yio sí ọkunrin kan ninu wọn ti yio le duro niwaju rẹ.

9. Joṣua si yọ si wọn lojijì; o si gòke lati Gilgali lọ ni gbogbo oru na.

10. OLUWA si fọ́ wọn niwaju Israeli, o si pa wọn ni ipakupa ni Gibeoni, o si lepa wọn li ọ̀na òke Beti-horoni, o si pa wọn dé Aseka, ati dé Makkeda.

11. O si ṣe, bi nwọn ti nsá niwaju Israeli, ti nwọn dé gẹrẹgẹrẹ Beti-horoni, OLUWA rọ̀ yinyin nla si wọn lati ọrun wá titi dé Aseka, nwọn si kú: awọn ti o ti ipa yinyin kú, o pọ̀ju awọn ti awọn ọmọ Israeli fi idà pa lọ.

12. Nigbana ni Joṣua wi fun OLUWA li ọjọ́ ti OLUWA fi awọn Amori fun awọn ọmọ Israeli, o si wi li oju Israeli pe, Iwọ, Õrùn, duro jẹ lori Gibeoni; ati Iwọ, Oṣupa, li afonifoji Aijaloni.

13. Õrùn si duro jẹ, oṣupa si duro, titi awọn enia fi gbẹsan lara awọn ọtá wọn. A kò ha kọ eyi nã sinu iwé Jaṣeri? Bẹ̃li õrùn duro li agbedemeji ọrun, kò si yára lati wọ̀ nìwọn ọjọ́ kan tọ̀tọ.

14. Kò sí ọjọ́ ti o dabi rẹ̀ ṣaju rẹ̀ tabi lẹhin rẹ̀, ti OLUWA gbọ́ ohùn enia: nitoriti OLUWA jà fun Israeli.

15. Joṣua si pada, ati gbogbo Israeli pẹlu rẹ̀, si ibudó ni Gilgali.

16. Ṣugbọn awọn ọba marun nì sá, nwọn si fara wọn pamọ́ ni ihò kan ni Makkeda.

17. A si sọ fun Joṣua pe, A ri awọn ọba marun ni ifarapamọ́ ni ihò ni Makkeda.

18. Joṣua si wipe, Ẹ yí okuta nla di ẹnu ihò na, ki ẹ si yàn enia sibẹ̀ lati ṣọ́ wọn:

Ka pipe ipin Joṣ 10