Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joṣ 10:30-39 Yorùbá Bibeli (YCE)

30. OLUWA si fi i lé Israeli lọwọ pẹlu, ati ọba rẹ̀: o si fi oju idà kọlù u, ati gbogbo ọkàn ti o wà ninu rẹ̀; kò kù ẹnikan ninu rẹ̀; o si ṣe si ọba rẹ̀ gẹgẹ bi o ti ṣe si ọba Jeriko.

31. Joṣua si kọja lati Libna lọ si Lakiṣi, ati gbogbo Israeli pẹlu rẹ̀, o si dótì i, o si fi ìja fun u.

32. OLUWA si fi Lakiṣi lé Israeli lọwọ, o si kó o ni ijọ́ keji, o si fi oju idà kọlù u, ati gbogbo ọkàn ti o wà ninu rẹ̀, gẹgẹ bi gbogbo eyiti o ṣe si Libna.

33. Nigbana ni Horamu ọba Geseri gòke lati ràn Lakiṣi lọwọ; Joṣua si kọlù u ati awọn enia rẹ̀, tobẹ̃ ti kò fi kù ẹnikan silẹ fun u.

34. Lati Lakiṣi Joṣua kọja lọ si Egloni, ati gbogbo Israeli pẹlu rẹ̀; nwọn si dótì i, nwọn si fi ijà fun u;

35. Nwọn si kó o li ọjọ́ na, nwọn si fi oju idà kọlù u, ati gbogbo ọkàn ti mbẹ ninu rẹ̀ li o parun patapata li ọjọ́ na, gẹgẹ bi gbogbo eyiti o ṣe si Lakiṣi.

36. Joṣua si gòke lati Egloni lọ si Hebroni, ati gbogbo Israeli pẹlu rẹ̀; nwọn si fi ijà fun u:

37. Nwọn si kó o, nwọn si fi oju idà kọlù u, ati ọba rẹ̀, ati gbogbo ilu rẹ̀, ati gbogbo ọkàn ti o wà ninu rẹ̀; kò kù enikan silẹ, gẹgẹ bi gbogbo eyiti o ṣe si Egloni; o si pa a run patapata, ati gbogbo ọkàn ti o wà ninu rẹ̀.

38. Joṣua si pada lọ si Debiri, ati gbogbo Israeli pẹlu rẹ̀; o si fi ijà fun u:

39. O si kó o, ati ọba rẹ̀, ati gbogbo ilu rẹ̀; nwọn si fi oju idà kọlù wọn; nwọn si pa gbogbo ọkàn ti mbẹ ninu rẹ̀ run patapata; kò si kù ẹnikan silẹ: gẹgẹ bi o ti ṣe si Hebroni, bẹ̃li o ṣe si Debiri, ati ọba rẹ̀; ati gẹgẹ bi o ti ṣe si Libna, ati ọba rẹ̀.

Ka pipe ipin Joṣ 10