Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 20:4-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. Nitori bayi li Oluwa wi, sa wò o, emi o fi ọ le idãmu lọwọ, pẹlu gbogbo awọn ọrẹ rẹ, nwọn o ṣubu nipa idà awọn ọta wọn, oju rẹ yio si ri i, emi o si fi gbogbo Juda le ọwọ ọba Babeli, on o si mu wọn lọ ni igbèkun si Babeli, yio si fi idà pa wọn.

5. Pẹlupẹlu emi o fi ọrọ̀ ilu yi, pẹlu ẽre rẹ̀ ati ohun iyebiye rẹ̀, ati gbogbo iṣura awọn ọba Juda li emi o fi le ọwọ awọn ọta wọn, ti yio jẹ wọn ti yio si mu wọn lọ si Babeli.

6. Ati iwọ, Paṣuri, ati gbogbo awọn ti o ngbe inu ile rẹ ni yio lọ si igbekun, iwọ o wá si Babeli, ati nibẹ ni iwọ o kú si, a o si sin ọ sibẹ, iwọ ati gbogbo ọrẹ rẹ ti iwọ ti sọ asọtẹlẹ eke fun.

7. Oluwa, iwọ ti fi ọ̀rọ rọ̀ mi, emi si gba rirọ̀! iwọ li agbara jù mi lọ, o si bori mi; emi di ẹni iyọ-ṣuti-si lojojumọ, gbogbo wọn ni ngàn mi!

8. Nitori lati igba ti mo ti sọ̀rọ, emi kigbe, mo ke, Iwa-agbara, ati iparun, nitori a sọ ọ̀rọ Oluwa di ohun ẹ̀gan ati itiju fun mi lojojumọ.

Ka pipe ipin Jer 20