Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 45:7-20 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Mo dá imọlẹ, mo si dá okunkun: mo ṣe alafia, mo si dá ibi: Emi Oluwa li o ṣe gbogbo wọnyi.

8. Kán silẹ, ẹnyin ọrun, lati oke wá, ki ẹ si jẹ ki ofurufu rọ̀ ododo silẹ; jẹ ki ilẹ ki o là, ki o si mu igbala jade; si jẹ ki ododo ki o hù soke pẹlu rẹ̀; Emi Oluwa li o dá a.

9. Egbe ni fun ẹniti o mbá Elẹda rẹ̀ jà, apãdi ninu awọn apãdi ilẹ! Amọ̀ yio ha wi fun ẹniti o mọ ọ pe, Kini iwọ nṣe? tabi iṣẹ rẹ pe, On kò li ọwọ́?

10. Egbe ni fun ẹniti o wi fun baba rẹ̀ pe, Kini iwọ bi? tabi fun obinrin nì pe, Kini iwọ bi?

11. Bayi li Oluwa wi, Ẹni-Mimọ Israeli, ati Ẹlẹda rẹ̀, Bere nkan ti mbọ̀ lọwọ mi, niti awọn ọmọ mi ọkunrin, ati niti iṣẹ ọwọ mi, ẹ paṣẹ fun mi.

12. Mo ti dá aiye, mo si ti da enia sori rẹ̀; Emi, ani ọwọ́ mi, li o ti nà awọn ọrun, gbogbo awọn ogun wọn ni mo si ti paṣẹ fun.

13. Mo ti gbe e dide ninu ododo, emi o si mu gbogbo ọ̀na rẹ̀ tọ́; on o kọ́ ilu mi, yio si dá awọn ondè mi silẹ: ki iṣe fun iye owo tabi ère, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.

14. Bayi li Oluwa wi, pe, Ere iṣẹ Egipti, ati ọjà Etiopia ati ti awọn ara Sabea, awọn enia ti o ṣigbọnlẹ yio kọja wá sọdọ rẹ, nwọn o si jẹ tirẹ: nwọn o tẹle ọ; ninu ẹwọ̀n ni nwọn o kọja wá, nwọn o foribalẹ fun ọ, nwọn o si bẹ̀ ọ, wipe, Nitotọ Ọlọrun wà ninu rẹ; kò si si ẹlomiran, kò si Ọlọrun miran.

15. Lõtọ iwọ li Ọlọrun ti o fi ara rẹ pamọ, Ọlọrun Israeli, Olugbala.

16. Oju yio tì wọn, gbogbo wọn o si dãmu pọ̀; gbogbo awọn ti nṣe ere yio si jumọ lọ si idãmu.

17. Ṣugbọn a o fi igbala ainipẹkun gba Israeli là ninu Oluwa: oju ki yio tì nyin, bẹ̃ni ẹ ki yio dãmu titi aiye ainipẹkun.

18. Nitori bayi li Oluwa wi, ẹniti o dá awọn ọrun; Ọlọrun tikararẹ̀ ti o mọ aiye, ti o si ṣe e; o ti fi idi rẹ̀ mulẹ, kò da a lasan, o mọ ọ ki a le gbe inu rẹ̀: Emi ni Oluwa; ko si ẹlomiran.

19. Emi kò sọrọ ni ikọkọ ni ibi okùnkun aiye: Emi kò wi fun iru-ọmọ Jakobu pe, Ẹ wá mi lasan: emi Oluwa li o nsọ ododo, mo fi nkan wọnni ti o tọ́ hàn.

20. Ko ara nyin jọ ki ẹ si wá; ẹ jọ sunmọ tosi, ẹnyin ti o salà ninu awọn orilẹ-ède: awọn ti o gbé igi ere gbigbẹ́ wọn kò ni ìmọ, nwọn si gbadura si ọlọrun ti ko le gba ni.

Ka pipe ipin Isa 45