Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 45:2-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

2. Emi o lọ siwaju rẹ, emi o si sọ ibi wiwọ́ wọnni di titọ́: emi o fọ ilẹkùn idẹ wọnni tũtũ, emi o si ke ọjá-irin si meji.

3. Emi o si fi iṣura okùnkun fun ọ, ati ọrọ̀ ti a pamọ nibi ikọkọ, ki iwọ le mọ̀ pe, emi Oluwa, ti o pè ọ li orukọ rẹ, li Ọlọrun Israeli.

4. Nitori Jakobu iranṣẹ mi, ati Israeli ayanfẹ mi, emi ti pè ọ li orukọ rẹ: mo ti fi apele kan fun ọ, bi iwọ ko tilẹ ti mọ̀ mi.

5. Emi li Oluwa, ko si ẹlomiran, kò si Ọlọrun kan lẹhin mi: mo dì ọ li àmure, bi iwọ kò tilẹ ti mọ̀ mi.

6. Ki nwọn le mọ̀ lati ila-õrun, ati lati iwọ-õrun wá pe, ko si ẹnikan lẹhin mi; Emi ni Oluwa, ko si ẹlomiran.

7. Mo dá imọlẹ, mo si dá okunkun: mo ṣe alafia, mo si dá ibi: Emi Oluwa li o ṣe gbogbo wọnyi.

8. Kán silẹ, ẹnyin ọrun, lati oke wá, ki ẹ si jẹ ki ofurufu rọ̀ ododo silẹ; jẹ ki ilẹ ki o là, ki o si mu igbala jade; si jẹ ki ododo ki o hù soke pẹlu rẹ̀; Emi Oluwa li o dá a.

9. Egbe ni fun ẹniti o mbá Elẹda rẹ̀ jà, apãdi ninu awọn apãdi ilẹ! Amọ̀ yio ha wi fun ẹniti o mọ ọ pe, Kini iwọ nṣe? tabi iṣẹ rẹ pe, On kò li ọwọ́?

10. Egbe ni fun ẹniti o wi fun baba rẹ̀ pe, Kini iwọ bi? tabi fun obinrin nì pe, Kini iwọ bi?

11. Bayi li Oluwa wi, Ẹni-Mimọ Israeli, ati Ẹlẹda rẹ̀, Bere nkan ti mbọ̀ lọwọ mi, niti awọn ọmọ mi ọkunrin, ati niti iṣẹ ọwọ mi, ẹ paṣẹ fun mi.

12. Mo ti dá aiye, mo si ti da enia sori rẹ̀; Emi, ani ọwọ́ mi, li o ti nà awọn ọrun, gbogbo awọn ogun wọn ni mo si ti paṣẹ fun.

13. Mo ti gbe e dide ninu ododo, emi o si mu gbogbo ọ̀na rẹ̀ tọ́; on o kọ́ ilu mi, yio si dá awọn ondè mi silẹ: ki iṣe fun iye owo tabi ère, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.

14. Bayi li Oluwa wi, pe, Ere iṣẹ Egipti, ati ọjà Etiopia ati ti awọn ara Sabea, awọn enia ti o ṣigbọnlẹ yio kọja wá sọdọ rẹ, nwọn o si jẹ tirẹ: nwọn o tẹle ọ; ninu ẹwọ̀n ni nwọn o kọja wá, nwọn o foribalẹ fun ọ, nwọn o si bẹ̀ ọ, wipe, Nitotọ Ọlọrun wà ninu rẹ; kò si si ẹlomiran, kò si Ọlọrun miran.

15. Lõtọ iwọ li Ọlọrun ti o fi ara rẹ pamọ, Ọlọrun Israeli, Olugbala.

16. Oju yio tì wọn, gbogbo wọn o si dãmu pọ̀; gbogbo awọn ti nṣe ere yio si jumọ lọ si idãmu.

17. Ṣugbọn a o fi igbala ainipẹkun gba Israeli là ninu Oluwa: oju ki yio tì nyin, bẹ̃ni ẹ ki yio dãmu titi aiye ainipẹkun.

18. Nitori bayi li Oluwa wi, ẹniti o dá awọn ọrun; Ọlọrun tikararẹ̀ ti o mọ aiye, ti o si ṣe e; o ti fi idi rẹ̀ mulẹ, kò da a lasan, o mọ ọ ki a le gbe inu rẹ̀: Emi ni Oluwa; ko si ẹlomiran.

Ka pipe ipin Isa 45