Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 45:14-25 Yorùbá Bibeli (YCE)

14. Bayi li Oluwa wi, pe, Ere iṣẹ Egipti, ati ọjà Etiopia ati ti awọn ara Sabea, awọn enia ti o ṣigbọnlẹ yio kọja wá sọdọ rẹ, nwọn o si jẹ tirẹ: nwọn o tẹle ọ; ninu ẹwọ̀n ni nwọn o kọja wá, nwọn o foribalẹ fun ọ, nwọn o si bẹ̀ ọ, wipe, Nitotọ Ọlọrun wà ninu rẹ; kò si si ẹlomiran, kò si Ọlọrun miran.

15. Lõtọ iwọ li Ọlọrun ti o fi ara rẹ pamọ, Ọlọrun Israeli, Olugbala.

16. Oju yio tì wọn, gbogbo wọn o si dãmu pọ̀; gbogbo awọn ti nṣe ere yio si jumọ lọ si idãmu.

17. Ṣugbọn a o fi igbala ainipẹkun gba Israeli là ninu Oluwa: oju ki yio tì nyin, bẹ̃ni ẹ ki yio dãmu titi aiye ainipẹkun.

18. Nitori bayi li Oluwa wi, ẹniti o dá awọn ọrun; Ọlọrun tikararẹ̀ ti o mọ aiye, ti o si ṣe e; o ti fi idi rẹ̀ mulẹ, kò da a lasan, o mọ ọ ki a le gbe inu rẹ̀: Emi ni Oluwa; ko si ẹlomiran.

19. Emi kò sọrọ ni ikọkọ ni ibi okùnkun aiye: Emi kò wi fun iru-ọmọ Jakobu pe, Ẹ wá mi lasan: emi Oluwa li o nsọ ododo, mo fi nkan wọnni ti o tọ́ hàn.

20. Ko ara nyin jọ ki ẹ si wá; ẹ jọ sunmọ tosi, ẹnyin ti o salà ninu awọn orilẹ-ède: awọn ti o gbé igi ere gbigbẹ́ wọn kò ni ìmọ, nwọn si gbadura si ọlọrun ti ko le gba ni.

21. Ẹ sọ ọ, ki ẹ si mu wá, lõtọ, ki nwọn ki o jọ gbimọ̀ pọ̀: tali o mu ni gbọ́ eyi lati igbãni wa? tali o ti sọ ọ lati igba na wá? emi Oluwa kọ? ko si Ọlọrun miran pẹlu mi; Ọlọrun ododo ati Olugbala; ko si ẹlomiran lẹhin mi.

22. Kọju si mi, ki a si gba nyin là, gbogbo opin aiye: nitori emi li Ọlọrun, ko si ẹlomiran.

23. Mo ti fi ara mi bura, ọ̀rọ na ti ti ẹnu ododo mi jade, ki yio si pada, pe, Gbogbo ẽkún yio kunlẹ fun mi, gbogbọ ahọn yio bura.

24. Lõtọ, a o wipe, ninu Oluwa li emi ni ododo ati agbara: sọdọ rẹ̀ ni gbogbo enia yio wá; oju o si tì gbogbo awọn ti o binu si i.

25. Ninu Oluwa li a o dá gbogbo iru-ọmọ Israeli lare, nwọn o si ṣogo.

Ka pipe ipin Isa 45