Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 44:1-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. ṢUGBỌN nisisiyi, gbọ́, iwọ Jakobu iranṣẹ mi, ati Israeli ẹniti mo ti yàn:

2. Bayi ni Oluwa wi, ẹniti o dá ọ, ti o mọ ọ lati inu wá, ti yio si ràn ọ lọwọ; Má bẹ̀ru, iwọ Jakobu, iranṣẹ mi; ati iwọ Jeṣuruni ti mo ti yàn.

3. Nitori emi o dà omi lu ẹniti ongbẹ ngbẹ, ati iṣàn-omi si ilẹ gbigbẹ: emi o dà ẹmi mi si iru rẹ, ati ibukun mi si iru-ọmọ rẹ.

4. Nwọn o si hù soke lãrin koriko, bi igi willo leti ipadò.

5. Ọkan yio wipe, ti Oluwa li emi, omiran yio si pe ara rẹ̀ nipa orukọ Jakobu; omiran yio si fi ọwọ́ rẹ̀ kọ pe, on ni ti Oluwa, yio si pe apele rẹ̀ nipa orukọ Israeli.

6. Bayi ni Oluwa wi, Ọba Israeli, ati Olurapada rẹ, Oluwa awọn ọmọ-ogun; Emi ni ẹni-ikini, ati ẹni-ikẹhin; ati lẹhin mi ko si Ọlọrun kan.

7. Tani yio si pè bi emi, ti yio si sọ ọ ti yio si tò o lẹsẹ-ẹsẹ fun mi, lati igbati mo ti yàn awọn enia igbani? ati nkan wọnni ti mbọ̀, ti yio si ṣẹ, ki nwọn fi hàn fun wọn.

8. Ẹ má bẹ̀ru, ẹ má si foyà; emi ko ha ti mu nyin gbọ́ lati igba na wá, nkò ha si ti sọ ọ? ẹnyin na ni ẹlẹri mi. Ọlọrun kan mbẹ lẹhin mi bi? kò si Apata kan, emi ko mọ̀ ọkan.

9. Asan ni gbogbo awọn ti ngbẹ ere; nkan iyebiye wọn ki yio si lerè; awọn tikala wọn li ẹlẹri ara wọn: nwọn kò riran, bẹ̃ni nwọn kò mọ̀; ki oju ba le tì wọn.

10. Tani yio gbẹ́ oriṣa, tabi ti yio dà ere ti kò ni ère kan?

11. Kiyesi i, oju o tì gbogbo awọn ẹgbẹ́ rẹ̀; awọn oniṣọna, enia ni nwọn: jẹ ki gbogbo wọn kò ara wọn jọ, ki nwọn dide duro; nwọn o bẹ̀ru, oju o si jumọ tì wọn.

12. Alagbẹdẹ rọ ãke kan, o ṣiṣẹ ninu ẹyín, o fi ọmọ-owú rọ ọ, o si fi agbara apá rẹ̀ ṣe e: ebi npa a pẹlu, agbara rẹ̀ si tan; ko mu omi, o si rẹ̀ ẹ.

13. Gbẹnàgbẹnà ta okùn rẹ̀, o si fi nkan pupa sàmi rẹ̀, o fi ìfá fá a, o si fi kọmpassi là a birikiti: o sì yá a li aworán ọkunrin, gẹgẹ bi ẹwà enia, ki o le ma gbe inu ile.

14. O bẹ́ igi kedari lu ilẹ fun ra rẹ̀, o si mu igi kipressi ati oaku, o si mu u le fun ra rẹ̀ ninu awọn igi igbó: o gbìn igi aṣi, ojò si mu u dagba.

15. Nigbana ni yio jẹ ohun idana fun enia: nitori yio mu ninu wọn, yio si fi yá iná; lõtọ, o dá iná, o si din akara, lõtọ, o ṣe ọlọrun fun ra rẹ̀, o si nsìn i; o gbẹ ẹ li ere, o si nforibalẹ fun u.

16. Apakan ninu rẹ̀ li o fi dá iná, apakan ninu rẹ̀ li o fi jẹ ẹran: o sun sisun, o si yo, o yá iná pẹlu, o si wipe, Ahã, ara mi gbona, mo ti ri iná.

17. Iyokù rẹ̀ li o si fi ṣe ọlọrun, ani ere gbigbẹ́ rẹ̀, o foribalẹ fun u, o sìn i, o gbadura si i, o si wipe, Gbà mi; nitori iwọ li ọlọrun mi.

18. Nwọn kò mọ̀, oye ko si ye wọn: nitori o dí wọn li oju, ki nwọn ki o má le ri; ati aiya wọn, ki oye ki o má le ye wọn.

Ka pipe ipin Isa 44