Tani yio si pè bi emi, ti yio si sọ ọ ti yio si tò o lẹsẹ-ẹsẹ fun mi, lati igbati mo ti yàn awọn enia igbani? ati nkan wọnni ti mbọ̀, ti yio si ṣẹ, ki nwọn fi hàn fun wọn.