Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 30:4-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. Nitori awọn olori rẹ̀ wá ni Soani, awọn ikọ̀ rẹ̀ de Hanesi.

5. Oju awọn enia kan ti kò li ère fun wọn tilẹ tì wọn, ti kò le ṣe iranwọ, tabi anfani, bikoṣe itiju ati ẹ̀gan pẹlu.

6. Ọ̀rọ-ìmọ niti awọn ẹranko gusu: sinu ilẹ wahala on àrodun, nibiti akọ ati abo kiniun ti wá, pamọlẹ ati ejò-ina ti nfò, nwọn o rù ọrọ̀ wọn li ejika awọn ọmọ kẹtẹkẹtẹ, ati iṣura wọn lori iké awọn ràkumi, sọdọ awọn enia kan ti kò li ère.

7. Egipti yio ṣe iranwọ lasan, kò si ni lari: nitorina ni mo ṣe kigbe pè e ni, Rahabu ti o joko jẹ.

8. Nisisiyi lọ, kọ ọ niwaju wọn si walã kan, si kọ ọ sinu iwe kan, ki o le jẹ fun igbà ti mbọ lai ati lailai:

9. Pe, ọlọ̀tẹ enia ni awọn wọnyi, awọn ọmọ eké, awọn ọmọ ti kò fẹ igbọ́ ofin Oluwa:

10. Ti nwọn wi fun awọn ariran pe, Máṣe riran; ati fun awọn wolĩ pe, Má sọtẹlẹ ohun ti o tọ́ fun wa, sọ nkan didùn fun wa, sọ asọtẹlẹ̀ itanjẹ.

11. Kuro li ọna na, yẹ̀ kuro ni ipa na, mu ki Ẹni-Mimọ Israeli ki o dẹkun kuro niwaju wa.

12. Nitorina bayi li Ẹni-Mimọ Israeli wi, Nitoriti ẹnyin gàn ọ̀rọ yi, ti ẹnyin si gbẹkẹle ininilara on ìyapa, ti ẹnyin si gbe ara nyin lé e;

13. Nitorina ni aiṣedede yi yio ri si nyin bi odi yiya ti o mura ati ṣubu, ti o tiri sode lara ogiri giga, eyiti wiwó rẹ̀ de lojijì, lojukanna.

14. Yio si fọ́ ọ bi fifọ́ ohun-èlo amọ̀ ti a fọ́ tútu; ti a kò dasi: tobẹ̃ ti a kì yio ri apãdi kan ninu ẹfọ́ rẹ̀ lati fi fọ̀n iná li oju ãro, tabi lati fi bù omi ninu ikũdu.

15. Nitori bayi ni Oluwa Jehofah, Ẹni-Mimọ Israeli wi; Ninu pipada on sisimi li a o fi gbà nyin là; ninu didakẹjẹ ati gbigbẹkẹle li agbara nyin wà; ṣugbọn ẹnyin kò fẹ.

16. Ṣugbọn ẹnyin wipe, Bẹ̃kọ; nitori ẹṣin li a o fi sá; nitorina li ẹnyin o ṣe sá: ati pe, Awa o gùn eyi ti o lè sare; nitorina awọn ti yio lepa nyin yio lè sare.

17. Ẹgbẹrun yio sá ni ibawi ẹnikan; ni ibawi ẹni marun li ẹnyin o sá: titi ẹnyin o fi kù bi àmi lori oke-nla, ati bi asia lori oke.

18. Nitorina ni Oluwa yio duro, ki o le ṣe ore fun nyin, ati nitori eyi li o ṣe ga, ki o le ṣe iyọ́nu si nyin: nitori Oluwa li Ọlọrun idajọ: ibukun ni fun gbogbo awọn ti o duro dè e.

Ka pipe ipin Isa 30