Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kro 6:31-36 Yorùbá Bibeli (YCE)

31. Ki nwọn ki o le bẹ̀ru rẹ, lati ma rìn li ọ̀na rẹ, li ọjọ gbogbo ti nwọn o wà ni ilẹ ti iwọ fi fun awọn baba wa.

32. Pẹlupẹlu niti alejo, ti kì iṣe inu Israeli, enia rẹ, ṣugbọn ti o ti ilẹ òkere jade wá nitori orukọ nla rẹ, ati ọwọ agbara rẹ ati ninà apa rẹ; bi nwọn ba wá ti nwọn ba si gbadura siha ile yi:

33. Ki iwọ ki o gbọ́ lati ọrun, ani lati ibugbe rẹ wá, ki o si ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti alejo na kepe ọ si; ki gbogbo enia aiye ki o le mọ̀ orukọ rẹ, ki nwọn ki o si le ma bẹ̀ru rẹ̀, bi Israeli enia rẹ, ki nwọn ki o le mọ̀ pe orukọ rẹ li a npè mọ ile yi ti emi kọ́.

34. Bi awọn enia rẹ ba jade lọ si ogun si ọta wọn li ọ̀na ti iwọ o rán wọn, ti nwọn ba si gbadura si ọ, siha ilu yi, ti iwọ ti yàn, ati ile ti emi ti kọ́ fun orukọ rẹ:

35. Ki iwọ ki o gbọ́ adura wọn ati ẹ̀bẹ wọn lati ọrun wa, ki o si mu ọ̀ran wọn duro.

36. Bi nwọn ba ṣẹ̀ si ọ (nitoriti kò si enia kan ti kì iṣẹ̀,) bi iwọ ba si binu si wọn, ti o si fi wọn le awọn ọta lọwọ, ti nwọn ba si kó wọn ni igbekun lọ si ilẹ ti o jìna rére, tabi ti o wà nitosi.

Ka pipe ipin 2. Kro 6