Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kro 6:29-34 Yorùbá Bibeli (YCE)

29. Adura ki adura, tabi ẹ̀bẹ ki ẹ̀bẹ ti a ba ti ọdọ ẹnikẹni gbà, tabi ọdọ gbogbo Israeli enia rẹ, nigbati olukuluku ba mọ̀ ipọnju rẹ̀, ati ibanujẹ rẹ̀, ti o ba si tẹ́ ọwọ rẹ̀ mejeji siha ile yi:

30. Ki iwọ ki o gbọ́ lati ọrun, ibugbe rẹ wá, ki o si dariji, ki o si san a fun olukuluku gẹgẹ bi gbogbo ọ̀na rẹ̀, bi iwọ ti mọ̀ ọkàn rẹ̀; (nitori iwọ nikanṣoṣo li o mọ̀ ọkàn awọn ọmọ enia:)

31. Ki nwọn ki o le bẹ̀ru rẹ, lati ma rìn li ọ̀na rẹ, li ọjọ gbogbo ti nwọn o wà ni ilẹ ti iwọ fi fun awọn baba wa.

32. Pẹlupẹlu niti alejo, ti kì iṣe inu Israeli, enia rẹ, ṣugbọn ti o ti ilẹ òkere jade wá nitori orukọ nla rẹ, ati ọwọ agbara rẹ ati ninà apa rẹ; bi nwọn ba wá ti nwọn ba si gbadura siha ile yi:

33. Ki iwọ ki o gbọ́ lati ọrun, ani lati ibugbe rẹ wá, ki o si ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti alejo na kepe ọ si; ki gbogbo enia aiye ki o le mọ̀ orukọ rẹ, ki nwọn ki o si le ma bẹ̀ru rẹ̀, bi Israeli enia rẹ, ki nwọn ki o le mọ̀ pe orukọ rẹ li a npè mọ ile yi ti emi kọ́.

34. Bi awọn enia rẹ ba jade lọ si ogun si ọta wọn li ọ̀na ti iwọ o rán wọn, ti nwọn ba si gbadura si ọ, siha ilu yi, ti iwọ ti yàn, ati ile ti emi ti kọ́ fun orukọ rẹ:

Ka pipe ipin 2. Kro 6