Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kro 34:2-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

2. O si ṣe eyiti o tọ́ li oju Oluwa, o si rìn li ọ̀na Dafidi, baba rẹ̀, kò si yà si ọwọ ọtún tabi si òsi.

3. Nitori li ọdun kẹjọ ijọba rẹ̀, nigbati o si wà li ọdọmọde sibẹ, o bẹ̀rẹ si iwá Ọlọrun Dafidi, baba rẹ̀; ati li ọdun kejila, o bẹ̀rẹ si iwẹ̀ Juda ati Jerusalemu mọ́ kuro ninu ibi giga wọnni, ati ere-oriṣa, ati ere yiyá, ati ere didà.

4. Nwọn si wó pẹpẹ Baalimu lulẹ niwaju rẹ̀; ati awọn ere õrun ti o wà lori wọn li o ké lulẹ; ati awọn ere-oriṣa, ati awọn ere yiyá, ati awọn ere didà, li o fọ tũtu, o sọ wọn di ekuru, o si gbọ̀n ọ sori isa-okú awọn ti o ti nrubọ́ si wọn.

5. O si sun egungun awọn alufa-oriṣa lori pẹpẹ wọn; o si wẹ Juda ati Jerusàlemu mọ́.

6. Bẹ̃li o si ṣe ni ilu Manasse wọnni ati ti Efraimu, ati ti Simeoni, ani titi de Naftali, o tú ile wọn yikakiri.

7. Nigbati o si fọ́ awọn pẹpẹ ati ère-oriṣa dilẹ, ti o si ti gún awọn ere yiyá di ẹ̀tu, ti o si ti ké gbogbo awọn ère-õrun lulẹ ni gbogbo ilẹ Israeli, o pada si Jerusalemu.

8. Njẹ li ọdun kejidilogun ijọba rẹ̀, nigbati o ti wẹ̀ ilẹ na mọ́, ati ile na, o rán Ṣafani, ọmọ Asaliah, ati Maaseiah, olori ilu na, ati Joa, ọmọ Joahasi, akọwe iranti, lati tun ile Oluwa Ọlọrun rẹ̀ ṣe.

9. Nigbati nwọn si de ọdọ Hilkiah, olori alufa, nwọn fi owo na ti a mu wá sinu ile Ọlọrun le e lọwọ, ti awọn ọmọ Lefi, ti o ntọju ilẹkun, ti kójọ lati ọwọ Manasse ati Efraimu, ati lati ọdọ gbogbo awọn iyokù Israeli, ati lati gbogbo Juda ati Benjamini: nwọn si pada si Jerusalemu.

10. Nwọn si fi i le ọwọ awọn ti nṣiṣẹ na, ti nṣe alabojuto iṣẹ ile Oluwa, nwọn si fi i fun awọn aṣiṣẹ ti nṣiṣẹ ile Oluwa, lati tun ile na ṣe:

11. Awọn ọlọnà ati awọn kọlekọle ni nwọn fifun lati ra okuta gbigbẹ́, ati ìti-igi fun isopọ̀, ati lati tẹ́ ile wọnni ti awọn ọba Juda ti bajẹ.

12. Awọn ọkunrin na fi otitọ ṣiṣẹ na: awọn alabojuto wọn ni Jahati ati Obadiah, awọn ọmọ Lefi, ninu awọn ọmọ Merari; ati Sekariah ati Meṣullamu, ninu awọn ọmọ Kohati, lati mu iṣẹ lọ; ati gbogbo awọn ọmọ Lefi, ti o ni ọgbọ́n ohun-elo orin.

13. Nwọn si wà lori awọn alãru, ati awọn alabojuto gbogbo awọn ti nṣiṣẹ, ninu ìsinkisin ati ninu awọn ọmọ Lefi ni akọwe, ati olutọju ati adèna.

Ka pipe ipin 2. Kro 34