Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kro 23:1-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. ATI li ọdun keje, Jehoiada mu ọkàn le, o si ba awọn olori ọrọrún dá majẹmu pẹlu, ani Asariah, ọmọ Jerohamu ati Iṣmaeli, ọmọ Jehohanani, ati Asariah ọmọ Obedi, ati Maaseiah, ọmọ Adaiah, ati Eliṣafati ọmọ Sikri.

2. Nwọn si lọ kakiri ni Juda, nwọn si kó awọn ọmọ Lefi jọ lati inu gbogbo ilu Juda, ati olori awọn baba ni Israeli, nwọn si wá si Jerusalemu.

3. Gbogbo ijọ enia si ba ọba dá majẹmu ni ile Ọlọrun. O si wi fun wọn pe, Kiyesi i, ọmọ ọba ni yio jọba, gẹgẹ bi Oluwa ti wi niti awọn ọmọ Dafidi.

4. Eyi li ohun ti ẹnyin o ṣe; Idamẹta nyin yio wọle li ọjọ isimi, ninu awọn alufa ati ninu awọn ọmọ Lefi, ti yio ṣe adena iloro;

5. Idamẹta yio wà ni ile ọba: idamẹta yio si wà ni ẹnu-ọ̀na ti a npè ni ile Ipilẹ: ati gbogbo enia yio wà li àgbala ile Oluwa.

6. Ṣugbọn ẹ máṣe jẹ ki ẹnikan ki o wọ̀ ile Oluwa wá, bikoṣe awọn alufa, ati awọn ti nṣe iranṣẹ fun awọn ọmọ Lefi: nwọn o wọle, nitori mimọ́ ni nwọn: gbogbo awọn enia yio si ṣọ́ ẹṣọ́ Oluwa.

7. Awọn ọmọ Lefi yio yi ọba ka kakiri, olukuluku pẹlu ohun ijà rẹ̀ li ọwọ rẹ̀: ẹnikẹni ti o ba wá si iha ile na, a o si pa a: ṣugbọn ki ẹnyin ki o wà pẹlu ọba, nigbati o ba nwọ̀ ile, ati nigbati o ba njade.

8. Bẹ̃li awọn ọmọ Lefi ati gbogbo Juda ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti Jehoiada, alufa ti pa á ni aṣẹ, olukuluku si mu awọn enia rẹ̀ ti o nwọle li ọjọ isimi, pẹlu awọn ti o njade li ọjọ isimi nitori Jehoiada alufa, kò jọwọ awọn ẹgbẹ meji alufa lọwọ lọ.

9. Jehoiada alufa, si fi ọ̀kọ ati asà, ati apata wọnni ti iti ṣe ti Dafidi ọba, ti o ti wà ni ile Ọlọrun, fun awọn balogun ọrọrun.

10. O si tò gbogbo awọn enia tì ọba kakiri olukuluku pẹlu ohun ijà rẹ̀ li ọwọ rẹ̀, lati apa ọtún ile na titi de apa òsi ile na, lẹba pẹpẹ ati lẹba ile na.

11. Nigbana ni nwọn mu ọmọ ọba jade wá, nwọn si fi ade fun u ati iwe ẹri na, nwọn si fi i jọba: Jehoiada ati awọn ọmọ rẹ̀ si fi ororo yàn a, nwọn si wipe, Ki ọba ki o pẹ.

12. Nigbati Ataliah gbọ́ ariwo awọn enia, ti nwọn nsare lọ sibẹ, ti nwọn si nyìn ọba, o si tọ awọn enia na wá sinu ile Oluwa:

Ka pipe ipin 2. Kro 23