Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kro 20:26-36 Yorùbá Bibeli (YCE)

26. Ati li ọjọ kẹrin nwọn kó ara wọn jọ li afonifoji Ibukún, nitori nibẹ ni nwọn fi ibukún fun Oluwa, nitorina ni a ṣe npe orukọ ibẹ na ni, Afonifoji Ibukún, titi di oni.

27. Nigbana ni nwọn yipada, gbogbo awọn ọkunrin Juda ati Jerusalemu, ati Jehoṣafati niwaju wọn lati pada lọ si Jerusalemu pẹlu ayọ̀; nitori ti Oluwa ti mu wọn yọ̀ lori awọn ọta wọn.

28. Nwọn si wá si Jerusalemu pẹlu ohun-elo orin, ati duru ati ipè si ile Oluwa.

29. Ibẹ̀ru Ọlọrun si wà lara gbogbo ijọba ilẹ wọnni, nigbati nwọn gbọ́ pe Oluwa ti ba awọn ọta Israeli jà.

30. Bẹ̃ni ijọba Jehoṣafati wà li alafia: nitoriti Ọlọrun rẹ̀ fun u ni isimi yikakiri.

31. Jehoṣafati si jọba lori Juda: o si wà li ẹni ọdun marundilogoji, nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ọdun mẹdọgbọn ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ si ni Asuba, ọmọbinrin Ṣilhi.

32. O si rìn li ọ̀na Asa, baba rẹ̀, kò si yà kuro ninu rẹ̀, o nṣe eyi ti o tọ́ li oju Oluwa.

33. Sibẹ kò mu ibi giga wọnni kuro: pẹlupẹlu awọn enia na kò si fi ọkàn wọn fun Ọlọrun awọn baba wọn rara.

34. Ati iyokù iṣe Jehoṣafati, ti iṣaju ati ti ikẹhin, kiyẹsi i, a kọ wọn sinu iwe Jehu, ọmọ Hanani, a si ti fi i sinu iwe awọn ọba Israeli.

35. Ati lẹhin eyi ni Jehoṣafati, ọba Juda, dà ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ Ahasiah, ọba Israeli, ẹniti o ṣe buburu gidigidi:

36. O si dà ara rẹ̀ pọ̀ mọ ọ lati kan ọkọ̀ lati lọ si Tarṣiṣi: nwọn si kàn ọkọ̀ ni Esion-Geberi.

Ka pipe ipin 2. Kro 20