Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Sam 6:5-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

5. Nitorina ẹnyin o ya ere iyọdi nyin, ati ere ẹ̀liri nyin ti o bà ilẹ na jẹ; ẹnyin o si fi ogo fun Ọlọrun Israeli: bọya yio mu ọwọ́ rẹ̀ fẹrẹ lara nyin, ati lara awọn ọlọrun nyin, ati kuro lori ilẹ nyin,

6. Njẹ ẽtiṣe ti ẹnyin fi se aiya nyin le, bi awọn ara Egipti ati Farao ti se aiya wọn le? nigbati o ṣiṣẹ iyanu nla larin wọn, nwọn kò ha jẹ ki awọn enia na lọ bi? nwọn si lọ.

7. Nitorina ẹ ṣe kẹkẹ titun kan nisisiyi, ki ẹ si mu abo malu meji ti o nfi ọmu fun ọmọ, eyi ti kò ti igbà ajaga si ọrun ri, ki ẹ si so o mọ kẹkẹ́ na, ki ẹnyin ki o si mu ọmọ wọn kuro lọdọ wọn wá ile.

8. Ki ẹnyin ki o si gbe apoti Oluwa nì ka ori kẹkẹ̀ na, ki ẹnyin ki o si fi ohun elo wura wọnni ti ẹnyin dá fun u nitori ẹbọ ọrẹ irekọja, ninu apoti kan li apakan rẹ̀; ki ẹnyin rán a, yio si lọ.

9. Ki ẹ si kiyesi i, bi o ba lọ si ọ̀na agbegbe tirẹ̀ si Betṣemeṣi, a jẹ pe on na li o ṣe wa ni buburu yi: ṣugbọn bi kò ba ṣe bẹ̃, nigbana li awa o to mọ̀ pe, ki iṣe ọwọ́ rẹ̀ li o lù wa, ṣugbọn ẽṣi li o ṣe si wa.

10. Awọn ọkunrin na si ṣe bẹ̃: nwọn si mu abo malu meji; ti nfi ọmu fun ọmọ, nwọn si dè wọn mọ kẹkẹ́ na, nwọn si se ọmọ wọn mọ ile.

11. Nwọn gbe apoti Oluwa wa lori kẹkẹ́ na, apoti pẹlu ẹ̀liri wura na, ati ere iyọdí wọn.

12. Awọn abo malu na si lọ tàra si ọ̀na Betṣemeṣi, nwọn si nke bi nwọn ti nlọ li ọ̀na opopo, nwọn kò yà si ọtún tabi si osì; awọn ijoye Filistini tẹle wọn lọ si agbegbe Betṣemeṣi.

13. Awọn ara Betṣemeṣi nkore alikama wọn li afonifoji: nwọn gbe oju wọn soke, nwọn si ri apoti na, nwọn si yọ̀ lati ri i.

14. Kẹkẹ́ na si wọ inu oko Joṣua, ara Betṣemeṣi, o si duro nibẹ, ibi ti okuta nla kan gbe wà: nwọn la igi kẹkẹ na, nwọn si fi malu wọnni ru ẹbọ sisun si Oluwa.

15. Awọn ọmọ Lefi si sọ apoti Oluwa na kalẹ, ati apoti ti o wà pẹlu rẹ̀, nibiti ohun elo wura wọnni gbe wà, nwọn si fi le ori okuta nla na: awọn ọkunrin Betṣemeṣi si ru ẹbọ sisun ati ẹbọ si Oluwa li ọjọ na.

16. Nigbati awọn ijoye Filistini marun si ri i, nwọn tun yipada lọ si Ekroni li ọjọ kanna,

17. Wọnyi ni iyọdi wura ti awọn Filistini dá fun irubọ si Oluwa; ọkan ti Aṣdodu, ọkan ti Gasa, ọkan ti Aṣkeloni, ọkan ti Gati, ọkan ti Ekroni.

18. Ẹliri wura na si ri gẹgẹ bi iye gbogbo ilu awọn Filistini ti o jasi ti awọn ijoye marun na, ati ilu, ati ilu olodi, ati awọn ileto, titi o fi de ibi okuta nla Abeli, lori eyi ti nwọn gbe apoti Oluwa kà: okuta eyiti o wà titi di oni ninu oko Joṣua ara Betṣemeṣi.

Ka pipe ipin 1. Sam 6