Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Sam 28:1-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. O si ṣe, ni ijọ wọnni, awọn Filistini si ko awọn ogun wọn jọ, lati ba Israeli jà. Akiṣi si wi fun Dafidi pe, Mọ̀ dajudaju pe, iwọ o ba mi jade lọ si ibi ija, iwọ ati awọn ọmọkunrin rẹ.

2. Dafidi si wi fun Akiṣi pe, Nitotọ iwọ o si mọ̀ ohun ti iranṣẹ rẹ le ṣe. Akiṣi si wi fun Dafidi pe, Nitorina li emi o ṣe fi iwọ ṣe oluṣọ ori mi ni gbogbo ọjọ.

3. Samueli sì ti kú, gbogbo Israeli si sọkun rẹ̀, nwọn si sin i ni Rama ni ilu rẹ̀. Saulu si ti mu awọn abokusọ̀rọ-ọkunrin, ati awọn abokusọ̀rọ-obinrin kuro ni ilẹ na.

4. Awọn Filistini si ko ara wọn jọ, nwọn wá, nwọn si do si Ṣunemu: Saulu si ko gbogbo Israeli jọ, nwọn si tẹdo ni Gilboa.

5. Nigbati Saulu si ri ogun awọn Filistini na, on si bẹ̀ru, aiya rẹ̀ si warìri gidigidi.

6. Nigbati Saulu si bere lọdọ Oluwa, Oluwa kò da a lohùn nipa alá, nipa Urimu tabi nipa awọn woli.

7. Saulu si wi fun awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Ẹ ba mi wá obinrin kan ti o ni ẹmi abokusọ̀rọ, emi o si tọ ọ lọ, emi o si bere lọdọ rẹ̀. Awọn iranṣẹ rẹ̀ si wi fun u pe, Wõ, obinrin kan ni Endori ti o ni ẹmi abokusọ̀rọ.

8. Saulu si pa ara dà, o si mu aṣọ miran wọ̀, o si lọ, awọn ọmọkunrin meji si pẹlu rẹ̀, nwọn si wá si ọdọ obinrin na li oru: on si wipe, emi bẹ̀ ọ, fi ẹmi abokusọ̀rọ da nkan fun mi, ki o si mu ẹniti emi o darukọ rẹ̀ fun ọ wá oke fun mi.

9. Obinrin na si da a lohùn pe, Wõ, iwọ sa mọ̀ ohun ti Saulu ṣe, bi on ti ke awọn abokusọ̀rọ obinrin, ati awọn abokusọ̀rọ ọkunrin kuro ni ilẹ na; njẹ eha ṣe ti iwọ dẹkùn fun ẹmi mi, lati mu ki nwọn pa mi?

10. Saulu si bura fun u nipa Oluwa, pe, Bi Oluwa ti mbẹ lãye, ìya kan ki yio jẹ ọ nitori nkan yi.

11. Obinrin na si bi i pe, Tali emi o mu wá soke fun ọ? on si wipe, Mu Samueli goke fun mi wá.

12. Nigbati obinrin na si ri Samueli, o kigbe lohùn rara: obinrin na si ba Saulu sọrọ pe, Ẽṣe ti iwọ fi tan mi jẹ? nitoripe Saulu ni iwọ iṣe.

Ka pipe ipin 1. Sam 28