Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Sam 25:1-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. SAMUELI si kú; gbogbo enia Israeli si ko ara wọn jọ, nwọn sì sọkun rẹ̀, nwọn si sin i ninu ile rẹ̀ ni Rama. Dafidi si dide, o si sọkalẹ lọ si ijù Parani.

2. Ọkunrin kan si mbẹ ni Maoni, ẹniti iṣẹ rẹ̀ mbẹ ni Karmeli; ọkunrin na si pọ̀ gidigidi, o si ni ẹgbẹdogun agutan, ati ẹgbẹrun ewurẹ: o sì nrẹ irun agutan rẹ̀ ni Karmeli.

3. Orukọ ọkunrin na si njẹ Nabali, orukọ aya rẹ̀ si njẹ Abigaili; on si jẹ oloye obinrin, ati arẹwa enia; ṣugbọn onroro ati oniwa buburu ni ọkunrin; ẹni idile Kalebu li on si ṣe.

4. Dafidi si gbọ́ li aginju pe, Nabali nrẹ irun agutan rẹ̀.

5. Dafidi si ran ọmọkunrin mẹwa, Dafidi si sọ fun awọn ọdọmọkunrin na pe, Ẹ goke lọ si Karmeli, ki ẹ si tọ Nabali lọ, ki ẹ si ki i li orukọ mi.

6. Bayi li ẹ o si wi fun ẹniti o wà ni irọra pe, Alafia fun ọ, alafia fun ile rẹ, ati alafia fun ohun gbogbo ti iwọ ni.

7. Njẹ mo gbọ́ pe, awọn olùrẹrun mbẹ lọdọ rẹ; Wõ, awọn oluṣọ agutan rẹ ti wà lọdọ wa, awa kò ṣe wọn ni iwọsi kan, bẹ̃ni ohun kan ko si nù lọwọ wọn, ni gbogbo ọjọ ti nwọn wà ni Karmeli.

8. Bi awọn ọmọkunrin rẹ lere, nwọn o si sọ fun ọ. Nitorina jẹ ki awọn ọmọkunrin wọnyi ki o ri oju rere lọdọ rẹ; nitoripe awa sa wá li ọjọ rere: emi bẹ ọ, ohunkohun ti ọwọ́ rẹ ba bá, fi fun awọn iranṣẹ rẹ, ati fun Dafidi ọmọ rẹ.

9. Awọn ọmọkunrin Dafidi si lọ, nwọn si sọ fun Nabali gẹgẹ bi gbogbo ọ̀rọ wọnyi li orukọ Dafidi, nwọn si simi.

10. Nabali si da awọn iranṣẹ Dafidi lohùn, pe, Tani ijẹ Dafidi? tabi tani si njẹ ọmọ Jesse? ọ̀pọlọpọ iranṣẹ ni mbẹ nisisiyi ti nwọn sá olukuluku kuro lọdọ oluwa rẹ̀.

11. Njẹ ki emi ki o ha mu onjẹ mi, ati omi mi, ati ẹran mi ti mo pa fun awọn olùrẹrun mi, ki emi ki o si fi fun awọn ọkunrin ti emi kò mọ̀ ibi ti nwọn gbe ti wá?

12. Bẹ̃li awọn ọmọkunrin Dafidi si mu ọ̀na wọn pọ̀n, nwọn si pada, nwọn si wá, nwọn si rò fun u gẹgẹ bi gbogbo ọ̀rọ wọnyi.

Ka pipe ipin 1. Sam 25