SAMUELI si kú; gbogbo enia Israeli si ko ara wọn jọ, nwọn sì sọkun rẹ̀, nwọn si sin i ninu ile rẹ̀ ni Rama. Dafidi si dide, o si sọkalẹ lọ si ijù Parani.