Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Kro 22:3-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

3. Dafidi si pese irin li ọ̀pọlọpọ fun iṣo fun ilẹkun ẹnu-ọ̀na, ati fun ìde; ati idẹ li ọ̀pọlọpọ li aini iwọn;

4. Igi kedari pẹlu li ainiye: nitori awọn ara Sidoni, ati awọn ti Tire mu ọ̀pọlọpọ igi kedari wá fun Dafidi.

5. Dafidi si wipe, Solomoni ọmọ mi, ọdọmọde ni, o si rọ̀, ile ti a o si kọ́ fun Oluwa, a o si ṣe e tobi jọjọ, fun okiki ati ogo ka gbogbo ilẹ: nitorina emi o pese silẹ fun u. Bẹ̃ni Dafidi si pese silẹ lọ̀pọlọpọ, ki o to kú.

6. Nigbana li o pe Solomoni ọmọ rẹ̀, o si fi aṣẹ fun u lati kọ́le kan fun Oluwa Ọlọrun Israeli.

7. Dafidi si wi fun Solomoni pe, Ọmọ mi, bi o ṣe ti emi ni, o ti wà li ọkàn mi lati kọ́le kan fun orukọ Oluwa Ọlọrun mi:

8. Ṣugbọn ọ̀rọ Oluwa tọ̀ mi wá, wipe, Iwọ ti ta ẹ̀jẹ silẹ li ọ̀pọlọpọ, iwọ si ti ja ogun nlanla: iwọ kò gbọdọ kọ́ ile fun orukọ mi, nitoriti iwọ ta ẹ̀jẹ pipọ̀ silẹ niwaju mi.

9. Kiyesi i, a o bi ọmọ kan fun ọ, ẹniti yio ṣe enia isimi; emi o si fun u ni isimi lọdọ gbogbo awọn ọta rẹ̀ yika kiri: nitori orukọ rẹ̀ yio ma jẹ Solomoni, emi o si fi alafia ati idakẹjẹ fun Israeli li ọjọ aiye rẹ̀.

10. On o kọ ile kan fun orukọ mi; on o si jẹ ọmọ mi; emi o si jẹ baba fun u; emi o si fi idi itẹ ijọba rẹ̀ mulẹ lori Israeli lailai.

11. Njẹ ọmọ mi, ki Oluwa ki o pẹlu rẹ; iwọ si ma pọ̀ si i, ki o si kọ́ ile Oluwa Ọlọrun rẹ, bi o ti sọ nipa tirẹ.

12. Kiki ki Oluwa ki o fun ọ li ọgbọ́n ati oye, ki o si fun ọ li aṣẹ niti Israeli, ki iwọ ki o le pa ofin Oluwa Ọlọrun rẹ mọ́.

13. Nigbana ni iwọ o ma pọ̀ si i, bi iwọ ba ṣe akiyesi lati mu aṣẹ ati idajọ ti Oluwa pa fun Mose ṣẹ niti Israeli: mura giri ki o si ṣe onigboya, má bẹ̀ru bẹ̃ni ki aiya ki o máṣe fò ọ.

14. Si kiyesi i, ninu ipọnju mi, emi ti pèse fun ile Oluwa na, ọkẹ marun talenti wura, ati ẹgbẹrun ẹgbẹrun talenti fadakà; ati ti idẹ, ati ti irin, laini ìwọn; nitori ọ̀pọlọpọ ni: ati ìti-igi ati okuta ni mo ti pèse; iwọ si le wá kún u.

15. Pẹlupẹlu awọn oniṣẹ mbẹ fun ọ lọpọlọpọ, awọn gbẹnagbẹna ati awọn oniṣọna okuta ati igi ati onirũru ọlọgbọ́n enia fun onirũru iṣẹ.

16. Niti wura, fadakà ati idẹ, ati irin, kò ni ìwọn. Nitorina dide ki o si ma ṣiṣẹ, ki Oluwa ki o si pẹlu rẹ.

Ka pipe ipin 1. Kro 22