Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. A. Ọba 8:30-36 Yorùbá Bibeli (YCE)

30. Ki o si tẹtisilẹ si ẹ̀bẹ iranṣẹ rẹ ati ti Israeli, enia rẹ, ti nwọn o gbadura siha ibi yi: ki o si gbọ́ li ọrun, ibugbe rẹ! gbọ́, ki o si darijì.

31. Bi ẹnikan ba ṣẹ̀ si ẹnikeji rẹ̀, ti a si fi ibura le e lati mu u bura, bi ibura na ba si de iwaju pẹpẹ rẹ ni ile yi:

32. Nigbana ni ki o gbọ́ li ọrun, ki o si ṣe, ki o si dajọ awọn iranṣẹ rẹ, ni didẹbi fun enia buburu, lati mu ọ̀na rẹ̀ wá si ori rẹ̀; ati ni didare fun olõtọ, lati fun u gẹgẹ bi ododo rẹ̀.

33. Nigbati a ba lù Israeli, enia rẹ bòlẹ niwaju awọn ọ̀ta, nitoriti nwọn dẹṣẹ si ọ, ti nwọn ba si yipada si ọ, ti nwọn si jẹwọ orukọ rẹ, ti nwọn si gbadura, ti nwọn si bẹ̀bẹ lọdọ rẹ ni ile yi:

34. Nigbana ni ki o gbọ́ li ọrun, ki o si dari ẹ̀ṣẹ Israeli, enia rẹ jì, ki o si mu wọn pada wá si ilẹ ti iwọ ti fi fun awọn baba wọn.

35. Nigbati a ba sé ọrun mọ, ti kò si òjo, nitoriti nwọn ti dẹṣẹ si ọ: bi nwọn ba gbadura si iha ibi yi, ti nwọn si jẹwọ orukọ rẹ, bi nwọn ba si yipada kuro ninu ẹ̀ṣẹ wọn, nigbati iwọ ba pọ́n wọn li oju.

36. Nigbana ni ki o gbọ́ li ọrun, ki o si dari ẹ̀ṣẹ awọn iranṣẹ rẹ jì, ati ti Israeli, enia rẹ, nigbati o kọ́ wọn li ọ̀na rere ninu eyiti nwọn iba mã rin, ki o si rọ̀ òjo si ilẹ rẹ, ti iwọ ti fi fun enia rẹ ni ilẹ-ini.

Ka pipe ipin 1. A. Ọba 8