Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. A. Ọba 8:19-31 Yorùbá Bibeli (YCE)

19. Ṣibẹ̀ iwọ kì yio kọ́ ile na, ṣugbọn ọmọ rẹ ti yio ti inu rẹ jade, on ni yio kọ́ ile na fun orukọ mi.

20. Oluwa si mu ọ̀rọ rẹ̀ ṣẹ ti o ti sọ, emi si dide ni ipò Dafidi, baba mi, mo si joko lori itẹ́ Israeli, gẹgẹ bi Oluwa ti sọ, emi si kọ́ ile kan fun orukọ Oluwa, Ọlọrun Israeli.

21. Emi si ti ṣe àye kan nibẹ̀ fun apoti-ẹri, ninu eyiti majẹmu Oluwa gbe wà, ti o ti ba awọn baba wa dá, nigbati o mu wọn jade lati ilẹ Egipti wá.

22. Solomoni si duro niwaju pẹpẹ Oluwa, loju gbogbo ijọ enia Israeli, o si nà ọwọ́ rẹ̀ mejeji soke ọrun:

23. O si wipe, Oluwa Ọlọrun Israeli, kò si Ọlọrun ti o dabi rẹ loke ọrun, tabi ni isalẹ ilẹ, ti ipa majẹmu ati ãnu mọ pẹlu awọn iranṣẹ rẹ ti nfi gbogbo ọkàn wọn rin niwaju rẹ:

24. Ẹniti o ti ba iranṣẹ rẹ Dafidi, baba mi pa ohun ti iwọ ti ṣe ileri fun u mọ: iwọ fi ẹnu rẹ sọ pẹlu, o si ti fi ọwọ́ rẹ mu u ṣẹ, gẹgẹ bi o ti ri loni.

25. Njẹ nisisiyi, Oluwa Ọlọrun Israeli, ba iranṣẹ rẹ Dafidi, baba mi pa ohun ti iwọ ti ṣe ileri fun u mọ́ wipe, A kì yio fẹ ọkunrin kan kù li oju mi lati joko lori itẹ Israeli; kiki bi awọn ọmọ rẹ ba le kiyesi ọ̀na wọn, ki nwọn ki o mã rìn niwaju mi gẹgẹ bi iwọ ti rìn niwaju mi.

26. Njẹ nisisiyi, Ọlọrun Israeli, jẹ ki a mu ọ̀rọ rẹ ṣẹ, emi bẹ̀ ọ, ti iwọ ti sọ fun iranṣẹ rẹ, Dafidi baba mi.

27. Ṣugbọn nitõtọ Ọlọrun yio ha mã gbe aiye bi? wò o, ọrun ati ọrun awọn ọrun kò le gbà ọ; ambọ̀sì ile yi ti mo kọ́?

28. Sibẹ̀ iwọ ṣe afiyèsi adura iranṣẹ rẹ, ati si ẹbẹ rẹ̀, Oluwa Ọlọrun mi, lati tẹtisilẹ si ẹkun ati si adura, ti iranṣẹ rẹ ngbà niwaju rẹ loni:

29. Ki oju rẹ lè ṣi si ile yi li ọsan ati li oru, ani si ibi ti iwọ ti wipe: Orukọ mi yio wà nibẹ: ki iwọ ki o lè tẹtisilẹ si adura ti iranṣẹ rẹ yio gbà si ibi yi.

30. Ki o si tẹtisilẹ si ẹ̀bẹ iranṣẹ rẹ ati ti Israeli, enia rẹ, ti nwọn o gbadura siha ibi yi: ki o si gbọ́ li ọrun, ibugbe rẹ! gbọ́, ki o si darijì.

31. Bi ẹnikan ba ṣẹ̀ si ẹnikeji rẹ̀, ti a si fi ibura le e lati mu u bura, bi ibura na ba si de iwaju pẹpẹ rẹ ni ile yi:

Ka pipe ipin 1. A. Ọba 8