Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 48:2-20 Yorùbá Bibeli (YCE)

2. Ati ni àgbegbe Dani, lati ihà ila-õrun, de ihà iwọ-õrun, ipin kan, fun Aṣeri.

3. Ati ni àgbegbe Aṣeri, lati ihà ila-õrun, ani titi de ihà iwọ-õrun, ipin kan, fun Naftali.

4. Ati ni àgbegbe Naftali, lati ihà ila-õrun, de ihà iwọ-õrun, ipin kan, fun Manasse.

5. Ati ni àgbegbe Manasse, lati ihà ila-õrun, de ihà iwọ-õrun, ipin kan, fun Efraimu.

6. Ati ni àgbegbe Efraimu, lati ihà ila-õrun, ani titi de ihà iwọ-õrun, ipin kan, fun Reubeni.

7. Ati ni àgbegbe Reubeni, lati ihà ila-õrun, ani titi de ihà iwọ-õrun, ipin kan, fun Juda.

8. Ati ni àgbegbe Juda, lati ihà ila-õrun, de ihà iwọ-õrun ni yio jẹ ọrẹ ti ẹnyin o ta, ẹgbã-mejila, o le ẹgbẹrun ije ni ibú, ati ni gigùn, bi ọkan ninu awọn ipin iyokù, lati ihà ila-õrun, de ihà iwọ-õrun: ibi mimọ́ yio si wà lãrin rẹ̀.

9. Ọrẹ ti ẹnyin o si ta fun Oluwa yio jẹ ẹgbã-mejila, o le ẹgbẹrun ni gigùn, ati ẹgbã-marun ni ibú.

10. Ati fun wọn, ani fun awọn alufa, ni ọrẹ mimọ́ yi yio jẹ; ni ihà ariwa, ẹgbã-mejila, o le ẹgbẹrun ni gigùn, ati ni ihà iwọ-õrun, ẹgbã-marun ni ibú, ati ni ihà ila-õrun, ẹgbã-marun ni ibú, ati ni ihà gusu, ẹgbã-mejila, o le ẹgbẹrun ni gigùn: ibi mimọ́ yio si wà lãrin rẹ̀.

11. Yio jẹ ti awọn alufa ti a yà si mimọ́, ninu awọn ọmọ Sadoku; ti nwọn ti pa ilàna mi mọ, ti nwọn kò si ṣìna ni iṣìna awọn ọmọ Israeli, bi awọn Lefi ti ṣìna.

12. Ọrẹ ilẹ ti a si ta yi, yio jẹ ohun mimọ́ julọ fun wọn li àgbegbe awọn Lefi.

13. Ati ni ikọjusi àgbegbe awọn alufa, ni awọn Lefi yio ni ẹgbã-mejila, o le ẹgbẹrun ni gigùn, ati ẹgbã-marun ni ibú: gigùn gbogbo rẹ̀ yio jẹ ẹgbã-mejila o le ẹgbẹrun, ati ibú rẹ̀, ẹgbã-marun.

14. Nwọn kì yio si tà ninu rẹ̀, nwọn kì yio si fi ṣe paṣiparọ, bẹ̃ni nwọn kì yio si fi akọ́so ilẹ na si ọwọ́ ẹlomiran, nitoripe o jẹ mimọ́ fun Oluwa.

15. Ati ẹgbẹ̃dọgbọn ti o kù ni ibú, ni ikọjusi ẹgbã-mejila o le ẹgbẹrun na, yio jẹ ibi aimọ́ fun ilu-nla na, fun ibugbe, ati fun àgbegbe: ilu-nla na yio si wà lãrin rẹ̀.

16. Wọnyi ni yio si jẹ iwọ̀n rẹ̀; ni ihà ariwa, ẹgbã-meji o le ẹ̃dẹgbẹta, ati ni ihà gusu, ẹgbã-meji o le ẹ̃dẹgbẹta, ati ni ihà ila-õrun, ẹgbã-meji o le ẹ̃dẹgbẹta, ati ni ihà iwọ-õrun, ẹgbã-meji o le ẹ̃dẹgbẹta.

17. Awọn àgbegbe ilu-nla na yio jẹ niha ariwa, ãdọtalerugba, ati nihà gusu, ãdọtalerugba ati nihà ila-õrun, ãdọtalerugba, ati nihà iwọ-õrun, ãdọtalerugba.

18. Ati iyokù ni gigùn, ni ikọjusi ọrẹ ti ipin mimọ́ na, yio si jẹ ẹgbã-marun nihà ila-õrun, ati ẹgbã-marun nihà iwọ-õrun: yio si wà ni ikọjusi ọrẹ ipin mimọ́ na, ati ibisi rẹ̀ yio jẹ fun onjẹ fun awọn ti nsìn ni ilu-nla na.

19. Awọn ti mba nsìn ilu-nla na yio si ma sìn i, lati inu gbogbo ẹ̀ya Israeli.

20. Gbogbo ọrẹ na yio jẹ ẹgbã-mejila o le ẹgbẹrun, nipa ẹgbã-mejila o le ẹgbẹrun: ẹ o si ta ọrẹ mimọ́ na, igun mẹrẹrin lọgbọ̃gba pẹlu ini ilu-nla na.

Ka pipe ipin Esek 48