Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 44:5-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

5. Oluwa si wi fun mi pe, Ọmọ enia, fi iyè rẹ si i, si fi oju rẹ wò, si fi eti rẹ gbọ́ ohun gbogbo ti emi ti sọ fun ọ niti gbogbo aṣẹ ile Oluwa, ati ti gbogbo ofin rẹ̀; si fi iyè rẹ si iwọ̀nu ile nì, pẹlu gbogbo ijadelọ ibi-mimọ́ na.

6. Iwọ o si wi fun awọn ọlọ̀tẹ, ani fun ile Israeli, pe, Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; ki gbogbo ohun-irira nyin to fun nyin, ile Israeli,

7. Niti pe ẹ mu ọmọ-ajèji, alaikọla aiya, ati alaikọla ara wa, lati wà ni ibi-mimọ́ mi, lati sọ ọ di alailọ̀wọ, ani ile mi, nigbati ẹ rú akara mi, ọ̀ra ati ẹjẹ, nwọn si bà majẹmu mi jẹ nipa gbogbo ohun-irira nyin.

8. Ẹ kò si pa ibi-iṣọ́ ohun-mimọ́ mi mọ́: ṣugbọn ẹ ti yàn oluṣọ́ ibi-iṣọ́ inu ibi-mimọ́ mi fun ara nyin.

9. Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi: Gbogbo ọmọ àjeji, alaikọla aiya, tabi alaikọla ara kì yio wọ̀ inu ibi mimọ́ mi, ninu gbogbo ọmọ àjeji ti o wà lãrin awọn ọmọ Israeli.

10. Ṣugbọn awọn Lefi ti o ti lọ jina kuro lọdọ mi, ni ìṣina Israeli, ti nwọn ṣìna kuro lọdọ mi lẹhin oriṣa wọn: yio si rù aiṣedede wọn.

11. Nwọn o si jẹ iranṣẹ ni ibi mimọ́ mi, oluṣọ́ ẹnu-ọ̀na ile, nwọn o si ma ṣe iranṣẹ ni ile: awọn ni yio pa ọrẹ-ẹbọ sisun ati ẹbọ fun awọn enia, nwọn o si duro niwaju wọn lati ṣe iranṣẹ fun wọn.

12. Nitori ti nwọn ṣe iranṣẹ fun wọn niwaju òriṣa wọn, nwọn si jẹ ohun ìdugbolu aiṣedede fun ile Israeli: nitorina ni mo gbe ọwọ́ mi soke si wọn, ni Oluwa Ọlọrun wi, nwọn o si rù aiṣedede wọn.

13. Nwọn kì yio si sunmọ ọdọ mi, lati ṣiṣẹ alufa fun mi, tabi lati sunmọ gbogbo ohun-mimọ́ mi, ni ibi mimọ́ julọ: nwọn o si rù itijú wọn, ati ohun-irira wọn ti nwọn ti ṣe.

14. Emi o si ṣe wọn ni oluṣọ́ ibi-iṣọ́ ile, fun gbogbo iṣẹ rẹ̀, ati fun ohun gbogbo ti a o ṣe ninu rẹ̀.

15. Ṣugbọn awọn alufa awọn Lefi, awọn ọmọ Sadoku, ti o pa ibi-iṣọ ibi mimọ́ mi mọ, nigbati awọn ọmọ Israeli ṣìna kuro lọdọ mi, awọn ni yio sunmọ ọdọ mi lati ṣe iranṣẹ fun mi, nwọn o si duro niwaju mi lati rú ọrá ati ẹjẹ si mi, ni Oluwa Ọlọrun wi:

16. Awọn ni yio wá si ibi-mimọ́ mi, awọn ni o si sunmọ tabili mi, lati ṣe iranṣẹ fun mi, nwọn o si pa ibi-iṣọ́ mi mọ́.

17. Yio si ṣe pe, nigbati nwọn ba wá si ẹnu-ọ̀na agbalá ti inu, nwọn o wọ̀ ẹ̀wu ọ̀gbọ; irun agutan kì yio bọ́ si ara wọn, nigbati nwọn ba nṣe iranṣẹ ni ẹnu-ọ̀na agbalá ti inu, ati ninu ile.

18. Nwọn o si ni filà ọ̀gbọ li ori wọn, ṣòkoto ọ̀gbọ ni nwọn o si wọ̀ ni idí wọn; nwọn kì o si fi ohun ti imuni lãgùn dì amurè.

Ka pipe ipin Esek 44