18. Ati okuta itẹlẹ ti iha ẹnu-ọ̀na na ti o kọju si gigun ẹnu-ọ̀na, ani okuta itẹlẹ isalẹ.
19. O si wọ̀n ibú rẹ̀ lati iwaju ẹnu-ọ̀na isalẹ titi fi de iwaju àgbala inu ti ode, ọgọrun igbọnwọ niha ila-õrun ati niha ariwa.
20. Ẹnu-ọ̀na àgbala ode ti o kọju si ariwa, o wọ̀n gigun rẹ̀, ati ibu rẹ̀.
21. Awọn yará kékèké ibẹ̀ jẹ mẹta niha ìhin, mẹta nihà ọhun; awọn atẹrigba ibẹ ati iloro ibẹ jẹ gẹgẹ bi ìwọn ẹnu-ọ̀na ekini: gigùn rẹ̀ jẹ ãdọta igbọnwọ, ibú rẹ̀ si jẹ igbọnwọ mẹ̃dọgbọ̀n.
22. Ati fèrese wọn, ati iloro wọn, ati igi ọpẹ wọn jẹ gẹgẹ bi ìwọn ti ẹnu-ọ̀na ti o kọju si ọ̀na ila-õrun; nwọn si ba atẹgun meje gùn oke rẹ̀ lọ; awọn iloro na si mbẹ niwaju wọn.
23. Ati ẹnu-ọ̀na agbala inu ti o kọju si ẹnu-ọ̀na ti ariwa, ati ti ila-õrun; o si wọ̀n lati ẹnu-ọ̀na de ẹnu-ọ̀na, ọgọrun igbọnwọ.
24. O si mu mi lọ si ọ̀na gusù, si kiye si i, ẹnu-ọ̀na kan mbẹ li ọ̀na gusù: o si wọ̀n awọn atẹrigba wọn, ati ìloro wọn gẹgẹ bi ìwọn wọnyi.
25. Fèrese pupọ si mbẹ ninu rẹ̀ ati ninu iloro wọn yika, bi ferese wọnni: gigùn rẹ̀ jẹ ãdọta igbọnwọ, ibú rẹ̀ jẹ igbọnwọ mẹ̃dọgbọn.
26. Atẹ̀gun meje ni mbẹ lati bá gùn oke rẹ̀, ati awọn iloro rẹ̀ si mbẹ niwaju wọn: o si ni igi ọpẹ, ọkan nihà ìhin, ati ọkan nihà ọhún, lara awọn atẹrigbà rẹ̀.
27. Ati ẹnu-ọ̀na agbalá ti inu mbẹ li ọ̀na gusu; o si wọ̀n lati ẹnu-ọ̀na de ẹnu-ọ̀na li ọ̀na gusu, ọgọrun igbọnwọ.
28. O si mu mi wá si agbalá ti inu nipa ẹnu-ọ̀na gusu: o si wọ̀n ẹnu-ọ̀na gusu na gẹgẹ bi ìwọn wọnyi;
29. Ati awọn yará kékèké rẹ̀, ati atẹrigbà rẹ̀, ati iloro rẹ̀, gẹgẹ bi ìwọn wọnyi: ferese pupọ̀ si mbẹ nibẹ ati ni iloro rẹ̀ yika: o jẹ ãdọta igbọnwọ ni gigùn, igbọnwọ mẹ̃dọgbọn ni ibú.