Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 38:13-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Ṣeba, ati Dedani, ati awọn oniṣòwo Tarṣiṣi, pẹlu gbogbo awọn ọmọ kiniun wọn, yio si wi fun ọ pe, Ikogun ni iwọ wá kó? lati wá mu ohun ọdẹ li o ṣe gbá awọn ẹgbẹ́ rẹ jọ? lati wá rù fadaka ati wura lọ, lati wá rù ohun-ọsìn ati ẹrù, lati wá kó ikogun nla?

14. Nitorina, sọtẹlẹ, ọmọ enia, si wi fun Gogu pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Ni ijọ na nigbati awọn enia mi Israeli ba ngbe laibẹ̀ru, iwọ kì yio mọ̀?

15. Iwọ o si ti ipò rẹ wá lati iha ariwa, iwọ, ati ọ̀pọ enia pẹlu rẹ, gbogbo wọn li o ngùn ẹṣin, ẹgbẹ nla, ati ọ̀pọlọpọ ogun alagbara:

16. Iwọ o si goke wá si awọn enia mi Israeli, bi awọsanma lati bò ilẹ; yio si ṣe nikẹhin ọjọ, emi o si mu ọ dojukọ ilẹ mi, ki awọn orilẹ-ède ki o le mọ̀ mi, nigbati a o yà mi si mimọ́ ninu rẹ, niwaju wọn, iwọ Gogu.

17. Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Iwọ li ẹniti mo ti sọ̀rọ rẹ̀ nigba atijọ lati ọwọ́ awọn iranṣẹ mi awọn woli Israeli, ti nwọn sọtẹlẹ li ọjọ wọnni li ọdun pupọ pe, emi o mu ọ wá dojukọ wọn?

18. Yio si ṣe nigbakanna li ákoko ti Gogu yio wá dojukọ ilẹ Israeli, ni Oluwa Ọlọrun wi, ti irúnu mi yio yọ li oju mi.

19. Nitori ni ijowu mi ati ni iná ibinu mi ni mo ti sọ̀rọ, Nitõtọ li ọjọ na mimì nla kan yio wà ni ilẹ Israeli;

20. Awọn ẹja inu okun, ati awọn ẹiyẹ oju ọrun, ati awọn ẹranko inu igbó, ati ohun gbogbo ti nrakò lori ilẹ, ati gbogbo enia ti mbẹ loju ilẹ, yio si mì niwaju mi, a o si bì òke-nla ṣubu, ati gbogbo ibi giga yio ṣubu, olukuluku ogiri yio ṣubu lulẹ.

21. Emi o si pè idà si i lori gbogbo oke mi, ni Oluwa Ọlọrun wi: idà olukuluku yio si dojukọ arakunrin rẹ̀.

22. Emi o si fi ajàkalẹ arùn ati ẹjẹ ba a wijọ; emi o si rọ̀ ojò pupọ̀, ati yìnyin nla, iná ati imi-ọjọ, si i lori, ati sori áwọn ẹgbẹ rẹ̀, ati sori ọ̀pọlọpọ enia ti o wà pẹlu rẹ̀.

23. Emi o si gbe ara mi lèke, emi o si ya ara mi si mimọ́; emi o si di mimọ̀ loju ọ̀pọlọpọ orilẹ-ède, nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa.

Ka pipe ipin Esek 38