Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 26:9-21 Yorùbá Bibeli (YCE)

9. Yio si gbe ohun-ẹrọ ogun tì odi rẹ, yio si fi ãke rẹ̀ wó ile-iṣọ́ rẹ lulẹ.

10. Nitori ọ̀pọ awọn ẹṣin rẹ̀ ẽkuru wọn yio bò ọ: odi rẹ yio mì nipa ariwo awọn ẹlẹṣin, ati kẹkẹ́, ati kẹkẹ́ ogun, nigbati yio wọ̀ inu odi rẹ lọ, gẹgẹ bi enia ti wọ̀ inu ilu ti a fọ́.

11. Pátakò ẹṣin rẹ̀ ni yio fi tẹ̀ gbogbo ìta rẹ mọlẹ: on o fi idà pa awọn enia rẹ, ati ọwọ̀n lile rẹ yio wó lulẹ.

12. Nwọn o si fi ọrọ̀ rẹ ṣe ikogun, ati òwo rẹ ṣe ijẹ ogun; nwọn o si wo odi rẹ lulẹ, nwọn o si bà ile rẹ daradara jẹ: nwọn o si ko okuta rẹ, ati ìti igi-ìkọle rẹ, ati erùpẹ rẹ, dà si ãrin omi.

13. Emi o si mu ariwo orin rẹ dakẹ; ati iró dùru rẹ li a kì yio gbọ́ mọ.

14. Emi o si ṣe ọ bi ori apáta; iwọ o si jẹ ibi lati nà awọ̀n le lori; a kì yio kọ́ ọ mọ: nitori emi Oluwa li o ti sọ ọ, li Oluwa Ọlọrun wi.

15. Bayi li Oluwa Ọlọrun wi si Tire; awọn erekùṣu kì yio ha mì-titi nipa iró iṣubu rẹ, nigbati awọn ti o gbọgbẹ́ kigbe, nigbati a ṣe ipani li ãrin rẹ?

16. Nigbana li awọn ọmọ-alade okun yio sọ̀kalẹ kuro lori itẹ́ wọn, nwọn o si pa aṣọ igunwà wọn tì, nwọn o si bọ́ ẹ̀wu oniṣẹ-ọnà wọn: nwọn o fi ìwariri bò ara wọn; nwọn o joko lori ilẹ, nwọn o si warìri nigba-gbogbo, ẹnu o si yà wọn si ọ.

17. Nwọn o si pohunrere-ẹkun fun ọ, nwọn o si wi fun ọ pe, Bawo li ati pa ọ run, iwọ ti awọn èro okun ti ngbe inu rẹ̀, ilu olokikí, ti o lagbara li okun, on ati awọn ti o gbe inu rẹ̀, ẹniti o mu ẹ̀ru wọn wá sara gbogbo awọn ti o pàra ninu rẹ!

18. Nisisiyi ni awọn erekùṣu yio warìri li ọjọ iṣubu rẹ; nitõtọ, awọn erekùṣu ti o wà ninu okun li a o yọ lẹnu nigba atilọ rẹ.

19. Nitori bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Nigbati emi o sọ ọ di ahoro ilu, gẹgẹ bi ilu wọnni ti a kò gbe inu wọn; nigbati emi o si mu ibú wá sori rẹ, ati omi nla yio si bò ọ.

20. Nigbati emi o bá mu ọ walẹ pẹlu awọn ti o sọkalẹ sinu ihò, pẹlu awọn enia igbãni, ti emi o si gbe ọ kà ibi isalẹ ilẹ aiye, ni ibi ahoro igbãni, pẹlu awọn ti o sọkalẹ lọ si ihò, ki a máṣe gbe inu rẹ mọ́: emi o si gbe ogo kalẹ ni ilẹ awọn alãye;

21. Emi o si ṣe ọ ni ẹ̀ru, iwọ kì yio si si mọ́: bi a tilẹ wá ọ, sibẹ a kì yio tun ri ọ mọ́, li Oluwa Ọlọrun wi.

Ka pipe ipin Esek 26