Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 20:30-45 Yorùbá Bibeli (YCE)

30. Si wi fun ile Israeli pe, Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; A bà nyin jẹ́ gẹgẹ bi baba nyin? ẹnyin si ṣe agbère gẹgẹ bi ohun-irira wọn?

31. Nitori nigbati ẹnyin nta ọrẹ nyin, nigbati ẹnyin mu ọmọ nyin kọja lãrin iná, ẹnyin fi oriṣa nyin bà ara nyin jẹ́, ani titi o fi di oni oloni: ẹnyin o ha si bere lọwọ mi, Iwọ ile Israeli? Bi mo ti wà, ni Oluwa Ọlọrun wi, lọwọ mi kọ́ ẹnyin o bere.

32. Eyiti o si wá si iye nyin kì yio wà rara; ti ẹnyin wipe, Awa o wà bi awọn keferi, gẹgẹ bi idile awọn orilẹ-ède lati bọ igi ati okuta.

33. Bi mo ti wà, ni Oluwa Ọlọrun wi, nitõtọ nipa agbara ọwọ́, ati ninà apa, pẹlu irúnu ti a dà jade li emi o fi jọba lori nyin:

34. Emi o si mu nyin jade kuro lãrin awọn enia, emi o si ṣà nyin jọ lati ilẹ ti a ti tú nyin ka si, pẹlu ọwọ́ agbara, ati ninà apa, ati pẹlu irúnu ti a dà jade.

35. Emi o si mu nyin wá si aginju awọn enia, nibẹ ni emi o si bá nyin rojọ lojukoju.

36. Gẹgẹ bi mo ti dá awọn baba nyin lẹjọ li aginju ilẹ Egipti, bẹ̃ni emi o bá nyin rojọ, ni Oluwa Ọlọrun wi.

37. Emi o si mu nyin kọja labẹ ọpá, emi o si mu nyin wá si ìde majẹmu:

38. Emi o si ṣà awọn ọlọ̀tẹ kuro lãrin nyin, ati awọn olurekọja, emi o mu wọn jade kuro ni ilẹ ti wọn gbe ṣe atipo, nwọn kì yio si wọ ilẹ Israeli: ẹnyin o si mọ̀ pe emi ni Oluwa.

39. Bi o ṣe ti nyin, ile Israeli, Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi, Ẹ lọ, olukuluku sìn oriṣa rẹ̀, ati lẹhin eyi pẹlu, bi ẹnyin kì yio ba fi eti si mi: ṣugbọn ẹ máṣe fi ẹ̀bun nyin ati oriṣa nyin bà orukọ mimọ́ mi jẹ́ mọ.

40. Nitori lori oke mimọ́ mi, lori oke giga Israeli, ni Oluwa Ọlọrun wi, nibẹ ni gbogbo ile Israeli, gbogbo wọn ni ilẹ na, yio sìn mi: nibẹ ni emi o gbà wọn, nibẹ ni emi o si bere ẹbọ nyin, ati ọrẹ akọso nyin, pẹlu ohun mimọ́ nyin.

41. Emi o gbà nyin pẹlu õrùn didùn nyin, nigbati mo mu nyin jade kuro lãrin awọn enia, ti mo si ko nyin jọ lati ilẹ gbogbo nibiti a gbe ti tú nyin ká si; a o si yà mi si mimọ́ ninu nyin niwaju awọn keferi.

42. Ẹnyin o si mọ̀ pe emi ni Oluwa, nigbati emi o mu nyin de ilẹ Israeli, si ilẹ niti eyiti o gbe ọwọ́ mi soke lati fi fun awọn baba nyin.

43. Nibẹ li ẹnyin o ranti ọ̀na nyin, ati gbogbo iṣe nyin, ninu eyiti a ti bà nyin jẹ; ẹ o si sú ara nyin loju ara nyin nitori gbogbo buburu ti ẹnyin ti ṣe.

44. Ẹnyin o si mọ̀ pe emi ni Oluwa, nigbati emi ti ṣiṣẹ pẹlu nyin nitori orukọ mi, ki iṣe gẹgẹ bi ọ̀na buburu nyin, tabi gẹgẹ bi iṣe bibajẹ nyin, ẹnyin ile Israeli, ni Oluwa Ọlọrun wi.

45. Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe,

Ka pipe ipin Esek 20