Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 16:3-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

3. Si wipe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi si Jerusalemu; Ibi rẹ ati ilẹ ibi rẹ ni ati ilẹ Kenaani wá; ará Amori ni baba rẹ, ará Hiti si ni iyá rẹ.

4. Ati niti ìbi rẹ, a kò da ọ ni iwọ́ ni ijọ ti a bi ọ, bẹ̃ni a kò wẹ̀ ọ ninu omi lati mu ọ mọ́, a kò fi iyọ̀ pa ọ lara rara, bẹ̃ni a kò fi ọja wé ọ rara.

5. Kò si oju ti o kãnu fun ọ, lati ṣe ọkan ninu nkan wọnyi fun ọ, lati ṣe iyọnu si ọ; ṣugbọn ninu igbẹ li a gbe ọ sọ si, fun ikorira ara rẹ, ni ijọ ti a bi ọ.

6. Nigbati mo si kọja lọdọ rẹ, ti mo si ri ọ, ti a tẹ̀ ọ mọlẹ ninu ẹjẹ ara rẹ, mo wi fun ọ nigbati iwọ wà ninu ẹjẹ rẹ pe, Yè: nitõtọ, mo wi fun ọ nigbati iwọ wà ninu ẹjẹ rẹ pe, Yè.

7. Emi ti mu ọ bi si i bi irudi itàna ìgbẹ; iwọ si ti pọ̀ si i, o si ti di nla, iwọ si gbà ohun ọṣọ́ ti o ti inu ọṣọ́ wá: a ṣe ọmú rẹ yọ, irun rẹ si dagba, nigbati o jẹ pe iwọ ti wà nihoho ti o si wà goloto.

8. Nigbati mo si kọja lọdọ rẹ, ti mo si wò ọ; kiye si i, ìgba rẹ jẹ ìgba ifẹ; mo si nà aṣọ mi bò ọ, mo si bo ihoho rẹ: nitõtọ, mo bura fun ọ, mo si ba ọ da majẹmu, ni Oluwa Ọlọrun wi, iwọ si di temi.

9. Nigbana ni mo fi omi wẹ̀ ọ; nitõtọ, mo wẹ ẹjẹ rẹ kuro lara rẹ patapata, mo si fi ororo kùn ọ lara.

10. Mo wọ̀ ọ laṣọ oniṣẹ-ọnà pẹlu, mo si fi awọ̀ badgeri wọ̀ ọ ni bàta, mo si fi aṣọ ọ̀gbọ daradara di ọ ni amure yika, mo si fi aṣọ ṣẹ́dà bò ọ.

11. Mo fi ohun-ọṣọ ṣe ọ lọṣọ pẹlu, mo si fi júfu bọ̀ ọ lọwọ, mo si fi ẹ̀wọn kọ́ ọ li ọrùn.

12. Mo si fi oruka si ọ ni imú, mo si fi oruka bọ̀ ọ leti, mo si fi ade daradara de ọ lori.

13. Bayi ni a fi wura ati fadaka ṣe ọ lọṣọ; aṣọ rẹ si jẹ ọgbọ̀ daradara, ati ṣẹ́dà, ati aṣọ oniṣẹ-ọnà; iwọ jẹ iyẹfun daradara ati oyin, ati ororo: iwọ si ni ẹwà gidigidi, iwọ si gbilẹ di ijọba kan.

14. Okiki rẹ si kan lãrin awọn keferi nitori ẹwà rẹ: nitori iwọ pé nipa ẹwà mi, ti mo fi si ọ lara, ni Oluwa Ọlọrun wi.

Ka pipe ipin Esek 16