Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 16:2-20 Yorùbá Bibeli (YCE)

2. Ọmọ enia, jẹ ki Jerusalemu mọ̀ ohun irira rẹ̀.

3. Si wipe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi si Jerusalemu; Ibi rẹ ati ilẹ ibi rẹ ni ati ilẹ Kenaani wá; ará Amori ni baba rẹ, ará Hiti si ni iyá rẹ.

4. Ati niti ìbi rẹ, a kò da ọ ni iwọ́ ni ijọ ti a bi ọ, bẹ̃ni a kò wẹ̀ ọ ninu omi lati mu ọ mọ́, a kò fi iyọ̀ pa ọ lara rara, bẹ̃ni a kò fi ọja wé ọ rara.

5. Kò si oju ti o kãnu fun ọ, lati ṣe ọkan ninu nkan wọnyi fun ọ, lati ṣe iyọnu si ọ; ṣugbọn ninu igbẹ li a gbe ọ sọ si, fun ikorira ara rẹ, ni ijọ ti a bi ọ.

6. Nigbati mo si kọja lọdọ rẹ, ti mo si ri ọ, ti a tẹ̀ ọ mọlẹ ninu ẹjẹ ara rẹ, mo wi fun ọ nigbati iwọ wà ninu ẹjẹ rẹ pe, Yè: nitõtọ, mo wi fun ọ nigbati iwọ wà ninu ẹjẹ rẹ pe, Yè.

7. Emi ti mu ọ bi si i bi irudi itàna ìgbẹ; iwọ si ti pọ̀ si i, o si ti di nla, iwọ si gbà ohun ọṣọ́ ti o ti inu ọṣọ́ wá: a ṣe ọmú rẹ yọ, irun rẹ si dagba, nigbati o jẹ pe iwọ ti wà nihoho ti o si wà goloto.

8. Nigbati mo si kọja lọdọ rẹ, ti mo si wò ọ; kiye si i, ìgba rẹ jẹ ìgba ifẹ; mo si nà aṣọ mi bò ọ, mo si bo ihoho rẹ: nitõtọ, mo bura fun ọ, mo si ba ọ da majẹmu, ni Oluwa Ọlọrun wi, iwọ si di temi.

9. Nigbana ni mo fi omi wẹ̀ ọ; nitõtọ, mo wẹ ẹjẹ rẹ kuro lara rẹ patapata, mo si fi ororo kùn ọ lara.

10. Mo wọ̀ ọ laṣọ oniṣẹ-ọnà pẹlu, mo si fi awọ̀ badgeri wọ̀ ọ ni bàta, mo si fi aṣọ ọ̀gbọ daradara di ọ ni amure yika, mo si fi aṣọ ṣẹ́dà bò ọ.

11. Mo fi ohun-ọṣọ ṣe ọ lọṣọ pẹlu, mo si fi júfu bọ̀ ọ lọwọ, mo si fi ẹ̀wọn kọ́ ọ li ọrùn.

12. Mo si fi oruka si ọ ni imú, mo si fi oruka bọ̀ ọ leti, mo si fi ade daradara de ọ lori.

13. Bayi ni a fi wura ati fadaka ṣe ọ lọṣọ; aṣọ rẹ si jẹ ọgbọ̀ daradara, ati ṣẹ́dà, ati aṣọ oniṣẹ-ọnà; iwọ jẹ iyẹfun daradara ati oyin, ati ororo: iwọ si ni ẹwà gidigidi, iwọ si gbilẹ di ijọba kan.

14. Okiki rẹ si kan lãrin awọn keferi nitori ẹwà rẹ: nitori iwọ pé nipa ẹwà mi, ti mo fi si ọ lara, ni Oluwa Ọlọrun wi.

15. Ṣugbọn iwọ gbẹkẹle ẹwà ara rẹ, o si huwa panṣaga nitori okìki rẹ, o si dà gbogbo agbere rẹ sori olukuluku ẹniti nkọja: tirẹ̀ ni.

16. Iwọ si mu ninu ẹwù rẹ, iwọ si fi aṣọ alaràbarà ṣe ibi giga rẹ lọṣọ, o si hùwa panṣaga nibẹ: iru nkan bẹ̃ kì yio de, bẹ̃ni kì yio ri bẹ̃.

17. Iwọ si mu ohun ọṣọ́ ẹlẹwà rẹ ninu wura mi, ati ninu fadaka mi, ti mo ti fun ọ, iwọ si ṣe àworán ọkunrin fun ara rẹ, o si fi wọn ṣe panṣaga,

18. Iwọ si mu ẹwù oniṣẹ-ọnà rẹ, o si fi bò wọn: iwọ si gbe ororo mi ati turari mi kalẹ niwaju wọn.

19. Onjẹ mi pẹlu ti mo ti fun ọ, iyẹfun daradara, ati ororo, ati oyin, ti mo fi bọ́ ọ, iwọ tilẹ gbe e kalẹ niwaju wọn fun õrùn didùn: bayi li o si ri, ni Oluwa Ọlọrun wi.

20. Pẹlupẹlu iwọ ti mu awọn ọmọ rẹ ọkunrin ati awọn ọmọ rẹ obinrin, ti iwọ ti bi fun mi, awọn wọnyi ni iwọ si ti fi rubọ si wọn lati jẹ. Ohun kekere ha ni eyi ninu ìwa panṣaga rẹ,

Ka pipe ipin Esek 16