Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Eks 12:17-29 Yorùbá Bibeli (YCE)

17. Ẹ o si kiyesi ajọ aiwukàra; nitori li ọjọ́ na gan ni mo mú ogun nyin jade kuro ni ilẹ Egipti; nitorina ni ki ẹ ma kiyesi ọjọ́ na ni iran-iran nyin nipa ìlana lailai.

18. Li oṣù kini li ọjọ kẹrinla oṣù na li aṣalẹ li ẹ o jẹ àkara alaiwu, titi yio fi di ọjọ́ kọkanlelogun oṣù na li aṣalẹ.

19. Ni ọjọ́ meje ni ki a máṣe ri iwukàra ninu ile nyin: nitori ẹniti o ba jẹ eyiti a wu, ọkàn na li a o ke kuro ninu ijọ Israeli, iba ṣe alejò, tabi ẹniti a bi ni ilẹ na.

20. Ẹ kò gbọdọ jẹ ohunkohun ti a wu; ninu ibugbé nyin gbogbo li ẹnyin o jẹ àkara alaiwu.

21. Nigbana ni Mose pè gbogbo awọn àgba Israeli, o si wi fun wọn pe, Ẹ jade lọ imú ọdọ-agutan fun ara nyin, gẹgẹ bi idile nyin, ki ẹ si pa irekọja na.

22. Ẹnyin o si mú ìdi ewe-hissopu, ẹ o si fi bọ̀ ẹ̀jẹ ti o wà ninu awokoto, ẹ o si fi ẹ̀jẹ na ti o wà ninu awokoto kùn ara atẹrigba, ati opó ìha mejeji; ẹnikẹni ninu nyin kò si gbọdọ jade lati ẹnu-ọ̀na ile rẹ̀ titi yio fi di owurọ̀.

23. Nitoriti OLUWA yio kọja lati kọlù awọn ara Egipti; nigbati o ba si ri ẹ̀jẹ lara atẹrigba, ati lara opó ìha mejeji, OLUWA yio si rekọja ẹnu-ọ̀na na, ki yio jẹ ki apanirun ki o wọle nyin wá lati kọlù nyin.

24. Ẹ o si ma kiyesi nkan yi nipa ìlana fun ọ, ati fun awọn ọmọ rẹ lailai.

25. O si ṣe, nigbati ẹ ba dé ilẹ na ti OLUWA yio fi fun nyin, gẹgẹ bi o ti wi, bẹ̃li ẹ o si ma kiyesi ìsin yi.

26. Yio si ṣe nigbati awọn ọmọ nyin ba bi nyin pe, Eredi ìsin yi?

27. Ki ẹ wipe, Ẹbọ irekọja OLUWA ni, ẹniti o rekọja ile awọn ọmọ Israeli ni Egipti, nigbati o kọlù awọn ara Egipti, ti o si dá ile wa si. Awọn enia si tẹriba nwọn si sìn.

28. Awọn ọmọ Israeli si lọ, nwọn si ṣe bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose ati Aaroni, bẹ̃ni nwọn ṣe.

29. O si ṣe lãrin ọganjọ́ li OLUWA pa gbogbo awọn akọ́bi ni ilẹ Egipti, lati akọ́bi Farao lọ ti o joko lori itẹ́ rẹ̀ titi o fi dé akọ́bi ẹrú ti o wà ni túbu; ati gbogbo akọ́bi ẹran-ọ̀sin.

Ka pipe ipin Eks 12