Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Timoti Kinni 1:4-15 BIBELI MIMỌ (BM)

4. kí wọn má jókòó ti àwọn ìtàn tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ ati ìtàn ìrandíran tí kò lópin, tí ó máa ń mú àríyànjiyàn wá, dípò ẹ̀kọ́ nípa Ọlọrun tí a mọ̀ nípa igbagbọ.

5. Ìdí tí mo fi pa àṣẹ yìí ni láti ta ìfẹ́ àtọkànwá jí ninu rẹ, pẹlu ẹ̀rí ọkàn rere ati igbagbọ tí kò lẹ́tàn.

6. Àwọn mìíràn ti kùnà nípa irú èyí; wọ́n ti yipada sí ọ̀rọ̀ asán.

7. Wọn á fẹ́ máa kọ́ni ní òfin, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kò mọ ohun tí wọn ń sọ, ohun tí wọ́n sì ń sọ pẹlu ìdánilójú kò yé wọn.

8. A mọ̀ pé òfin jẹ́ ohun tí ó dára bí a bá lò ó bí ó ti tọ́.

9. A mọ èyí pé a kò ṣe òfin fún àwọn eniyan rere, bí kò ṣe fún àwọn oníwàkiwà ati àwọn alágídí, àwọn aláìbọ̀wọ̀ fún Ọlọrun ati àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, àwọn oníbàjẹ́ ati àwọn aláìbìkítà fún ohun mímọ́, àwọn tí wọn máa ń lu baba ati ìyá wọn,

10. àwọn àgbèrè, àwọn ọkunrin tí ó ń bá ọkunrin lòpọ̀, àwọn gbọ́mọgbọ́mọ, àwọn onírọ́, àwọn tí ó ń búra èké, ati àwọn tí ń ṣe àwọn nǹkan mìíràn tí ó lòdì sí ẹ̀kọ́ tí ó dára,

11. gẹ́gẹ́ bí ìyìn rere tí a fi lé mi lọ́wọ́, ìyìn rere Ọlọrun Ológo, tí ìyìn yẹ fún.

12. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Kristi Jesu Oluwa wa, ẹni tí ń fún mi ní agbára. Mo dúpẹ́ nítorí ó kà mí yẹ láti fún mi ní iṣẹ́ rẹ̀,

13. èmi tí ó jẹ́ pé tẹ́lẹ̀ rí mo kẹ́gàn rẹ̀, mo ṣe inúnibíni sí i, mo tún fi àbùkù kàn án. Ṣugbọn ó ṣàánú mi nítorí n kò mọ̀ọ́nmọ̀ ṣe é; ninu aigbagbọ ni mo ṣe é.

14. Ṣugbọn oore-ọ̀fẹ́ Oluwa wa pàpọ̀jù lórí mi, ati igbagbọ ati ìfẹ́ tí a ní ninu Kristi Jesu.

15. Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ yìí: ó dájú, ó sì yẹ ní gbígbà tọkàntọkàn, pé Kristi Jesu wá sinu ayé láti gba ẹlẹ́ṣẹ̀ là. Èmi yìí sì ni olórí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.

Ka pipe ipin Timoti Kinni 1