Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Romu 4:6-16 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Dafidi náà sọ̀rọ̀ nípa oríire ẹni tí Ọlọrun kà sí ẹni rere, láìwo iṣẹ́ tí ó ṣe. Ó ní,

7. “Ẹni tí Ọlọrun bá dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jì,tí Ọlọrun bo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀, ó ṣoríire.

8. Ẹni tí Oluwa kò ka ẹ̀ṣẹ̀ sí lọ́rùn sì ṣoríire.”

9. Ṣé ẹni tí ó kọlà nìkan ni ó ṣoríire ni, tabi ati ẹni tí kò kọlà náà? Ohun tí a sọ ni pé, “Ọlọrun ka igbagbọ sí iṣẹ́ rere fún Abrahamu.”

10. Ipò wo ni ó wà tí Ọlọrun fi kà á sí ẹni rere: lẹ́yìn tí ó ti kọlà ni tabi kí ó tó kọlà? Kì í ṣe lẹ́yìn tí ó ti kọlà, kí ó tó kọlà ni.

11. Ó gba àmì ìkọlà bí ẹ̀rí iṣẹ́ rere nípa igbagbọ tí ó ní nígbà tí kò ì tíì kọlà. Nítorí èyí, ó di baba fún gbogbo àwọn tí ó ní igbagbọ láì kọlà, kí Ọlọrun lè kà wọ́n sí ẹni rere;

12. ó sì di baba fún àwọn tí ó kọlà ṣugbọn tí wọn kò gbẹ́kẹ̀lé ilà tí wọ́n kọ, ṣugbọn tí wọn ń rìn ní irú ọ̀nà igbagbọ tí baba wa Abrahamu ní kí ó tó kọlà.

13. Nítorí kì í ṣe nítorí pé Abrahamu pa Òfin mọ́ ni Ọlọrun fi ṣe ìlérí fún òun ati ìran rẹ̀ pé yóo jogún ayé; nítorí ó gba Ọlọrun gbọ́ ni, Ọlọrun sì kà á sí ẹni rere.

14. Nítorí bí ó bá jẹ́ pé àwọn tí ń tẹ̀lé ètò Òfin ni yóo jogún ìlérí Ọlọrun, a jẹ́ pé ọ̀ràn àwọn tí ó dúró lórí igbagbọ di òfo, ìlérí Ọlọrun sì di òtúbáńtẹ́.

15. Nítorí òfin ni ó ń mú ibinu Ọlọrun wá. Ṣugbọn níbi tí kò bá sí òfin, kò sí ẹ̀ṣẹ̀.

16. Ìdí nìyí tí ìlérí náà fi jẹ́ ti igbagbọ, kí ó lè jẹ́ ọ̀fẹ́, kí ó sì lè fẹsẹ̀ múlẹ̀ fún gbogbo ọmọ Abrahamu. Kì í ṣe fún àwọn tí ó gba ètò ti Òfin nìkan, bíkòṣe fún ẹni tí ó bá ní irú igbagbọ tí Abrahamu ẹni tí ó jẹ́ baba fún gbogbo wa ní.

Ka pipe ipin Romu 4