Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Romu 4:12-25 BIBELI MIMỌ (BM)

12. ó sì di baba fún àwọn tí ó kọlà ṣugbọn tí wọn kò gbẹ́kẹ̀lé ilà tí wọ́n kọ, ṣugbọn tí wọn ń rìn ní irú ọ̀nà igbagbọ tí baba wa Abrahamu ní kí ó tó kọlà.

13. Nítorí kì í ṣe nítorí pé Abrahamu pa Òfin mọ́ ni Ọlọrun fi ṣe ìlérí fún òun ati ìran rẹ̀ pé yóo jogún ayé; nítorí ó gba Ọlọrun gbọ́ ni, Ọlọrun sì kà á sí ẹni rere.

14. Nítorí bí ó bá jẹ́ pé àwọn tí ń tẹ̀lé ètò Òfin ni yóo jogún ìlérí Ọlọrun, a jẹ́ pé ọ̀ràn àwọn tí ó dúró lórí igbagbọ di òfo, ìlérí Ọlọrun sì di òtúbáńtẹ́.

15. Nítorí òfin ni ó ń mú ibinu Ọlọrun wá. Ṣugbọn níbi tí kò bá sí òfin, kò sí ẹ̀ṣẹ̀.

16. Ìdí nìyí tí ìlérí náà fi jẹ́ ti igbagbọ, kí ó lè jẹ́ ọ̀fẹ́, kí ó sì lè fẹsẹ̀ múlẹ̀ fún gbogbo ọmọ Abrahamu. Kì í ṣe fún àwọn tí ó gba ètò ti Òfin nìkan, bíkòṣe fún ẹni tí ó bá ní irú igbagbọ tí Abrahamu ẹni tí ó jẹ́ baba fún gbogbo wa ní.

17. Gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Mo ti yàn ọ́ láti di baba fún ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè.” Níwájú Ọlọrun ni Abrahamu wà nígbà tí ó gba ìlérí yìí, níwájú Ọlọrun tí ó gbẹ́kẹ̀lé, Ọlọrun tí ó ń sọ òkú di alààyè, Ọlọrun tí ó ń pe àwọn ohun tí kò ì tíì sí jáde bí ẹni pé wọ́n wá.

18. Abrahamu retí títí, ó gbàgbọ́ pé òun yóo di baba fún ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti wí, pé, “Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ rẹ yóo rí.”

19. Igbagbọ rẹ̀ kò yẹ̀ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ro ti ara rẹ̀ tí ó ti di òkú tán, (nítorí ó ti tó ẹni ọgọrun-un ọdún) ó tún ro ti Sara tí ó yàgàn.

20. Kò fi aigbagbọ ṣiyèméjì sí ìlérí Ọlọrun. Kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ni igbagbọ rẹ̀ túbọ̀ lágbára sí i, ó fi ògo fún Ọlọrun

21. nítorí pé ó dá a lójú pé ẹni tí ó ṣe ìlérí lè mú un ṣẹ.

22. Ìdí rẹ̀ nìyí tí Ọlọrun fi ka igbagbọ rẹ̀ sí iṣẹ́ rere fún un.

23. Ṣugbọn kì í ṣe nípa òun nìkan ṣoṣo ni a kọ ọ́ pé a ka igbagbọ sí iṣẹ́ rere.

24. A kọ ọ́ nítorí ti àwa náà tí a óo kà sí ẹni rere, gbogbo àwa tí a ní igbagbọ ninu ẹni tí ó jí Jesu Oluwa wa dìde kúrò ninu òkú,

25. ẹni tí ó kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa, tí a sì jí dìde fún ìdáláre wa.

Ka pipe ipin Romu 4