Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Matiu 9:1-15 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Jesu wọ inú ọkọ̀, ó rékọjá sí òdìkejì òkun, ó bá dé ìlú ara rẹ̀.

2. Àwọn kan bá gbé arọ kan wá, ó dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn. Nígbà tí Jesu rí igbagbọ wọn, ó sọ fún arọ náà pé, “Ṣe ara gírí, ọmọ, a dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.”

3. Àwọn amòfin kan ń rò ninu ara wọn pé, “Ọkunrin yìí ń sọ̀rọ̀ àfojúdi sí Ọlọrun.”

4. Ṣugbọn Jesu mọ èrò inú wọn; ó bá bi wọ́n pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ń ro èrò burúkú ninu ọkàn yín?

5. Èwo ni ó rọrùn jù, láti sọ pé, ‘A dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ ni,’ tabi láti sọ pé, ‘Dìde, kí o máa rìn?’

6. Ṣugbọn kí ẹ lè mọ̀ pé Ọmọ-Eniyan ní àṣẹ ní ayé láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji eniyan ni.” Nígbà náà ni ó wá wí fún arọ náà pé “Dìde, gbé ibùsùn rẹ, máa lọ sí ilé rẹ.”

7. Arọ náà bá dìde, ó lọ sí ilé rẹ̀.

8. Ẹ̀rù ba àwọn eniyan tí wọn ń wo ohun tí ó ṣẹlẹ̀. Wọ́n fi ògo fún Ọlọrun tí ó fi irú àṣẹ bẹ́ẹ̀ fún eniyan.

9. Nígbà tí Jesu kúrò níbẹ̀, ó rí ọkunrin kan tí ó ń jẹ́ Matiu tí ó jókòó níbi tí ó ti ń gba owó-odè. Ó wí fún un pé, “Máa tẹ̀lé mi.” Kíá, ó bá dìde, ó ń tẹ̀lé e.

10. Matiu se àsè ní ilé rẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn agbowó-odè ati àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ni wọ́n wá, tí wọn ń bá Jesu ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ jẹun.

11. Nígbà tí àwọn Farisi rí i, wọ́n bi àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Kí ní ṣe tí olùkọ́ yín fi ń bá àwọn agbowó-odè ati àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ jẹun?”

12. Nígbà tí Jesu gbọ́, ó ní, “Àwọn tí ara wọn le kò nílò oníṣègùn bíkòṣe àwọn tí ara wọn kò dá.

13. Ẹ lọ kọ́ ìtumọ̀ gbolohun yìí: Ọlọrun sọ pé, ‘Àánú ṣíṣe ni mo fẹ́, kì í ṣe ẹbọ rírú.’ Nítorí náà kì í ṣe àwọn olódodo ni mo wá pè, bíkòṣe àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.”

14. Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n bi í pé, “Kí ló dé tí àwa ati àwọn Farisi ń gbààwẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ìgbà, ṣugbọn àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ kì í gbààwẹ̀?”

15. Jesu dá wọn lóhùn pé, “Àwọn ọ̀rẹ́ ọkọ iyawo kò lè máa ṣọ̀fọ̀ níwọ̀n ìgbà tí ọkọ iyawo bá wà lọ́dọ̀ wọn. Àkókò ń bọ̀ nígbà tí a óo gba ọkọ iyawo lọ́wọ́ wọn; wọn yóo máa gbààwẹ̀ nígbà náà.

Ka pipe ipin Matiu 9