Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Matiu 20:18-33 BIBELI MIMỌ (BM)

18. “Lílọ ni à ń lọ sí Jerusalẹmu yìí o, wọn óo fi Ọmọ-Eniyan lé àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin lọ́wọ́, wọn óo sì dá a lẹ́bi ikú.

19. Wọn óo fà á lé àwọn tí kì í ṣe Juu lọ́wọ́ láti fi ṣe ẹlẹ́yà, láti nà ati láti kàn mọ́ agbelebu. Ṣugbọn ní ọjọ́ kẹta a óo jí i dìde.”

20. Nígbà náà ni ìyá àwọn ọmọ Sebede wá sọ́dọ̀ Jesu pẹlu àwọn ọmọ rẹ̀. Ó kúnlẹ̀, ó ń bèèrè nǹkankan lọ́dọ̀ rẹ̀.

21. Jesu bi í pé, “Kí ni o fẹ́?”Ó ní, “Gbà pé kí àwọn ọmọ mi mejeeji yìí jókòó pẹlu rẹ ní ìjọba rẹ, ọ̀kan ní ọwọ́ ọ̀tún ekeji ní ọwọ́ òsì.”

22. Jesu dáhùn pé, “Ẹ kò mọ ohun tí ẹ̀ ń bèèrè. Ẹ lè mu ninu ife ìrora tí èmi yóo mu?”Wọ́n dá a lóhùn pé, “A lè mu ún.”

23. Ó sọ fún wọn pé, “Lódodo ẹ óo mu ninu ife mi, ṣugbọn láti jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi ati ní ọwọ́ òsì mi kò sí ní ìkáwọ́ mi láti fi fún ẹnikẹ́ni, ipò wọnyi wà fún àwọn tí a ti pèsè rẹ̀ sílẹ̀ fún láti ọ̀dọ̀ Baba mi.”

24. Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mẹ́wàá yòókù gbọ́, inú wọn ru sí àwọn tẹ̀gbọ́n-tàbúrò meji yìí.

25. Ṣugbọn Jesu pè wọ́n sọ́dọ̀, ó ní, “Ẹ mọ̀ pé àwọn aláṣẹ láàrin àwọn alaigbagbọ a máa jẹ ọlá lórí wọn, àwọn eniyan ńláńlá láàrin wọn a sì máa lo agbára lórí wọn.

26. Tiyín kò ní rí bẹ́ẹ̀. Ṣugbọn ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ jẹ́ pataki ninu yín níláti jẹ́ iranṣẹ yín.

27. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ jẹ́ aṣaaju yóo ṣe ẹrú fun yín.

28. Nítorí Ọmọ-Eniyan kò wá pé kí eniyan ṣe iranṣẹ fún un; ó wá láti ṣe iranṣẹ ni, ati láti fi ẹ̀mí rẹ̀ ṣe ìràpadà fún ọpọlọpọ eniyan.”

29. Bí Jesu ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ti ń jáde kúrò ní Jẹriko, ọ̀pọ̀ eniyan tẹ̀lé e.

30. Àwọn afọ́jú meji kan jókòó lẹ́bàá ọ̀nà. Nígbà tí wọ́n gbọ́ pé Jesu ń kọjá lọ, wọ́n kígbe pé, “Ọmọ Dafidi, ṣàánú wa.”

31. Ṣugbọn àwọn eniyan bá wọn wí pé kí wọ́n panu mọ́. Ṣugbọn ńṣe ni wọ́n túbọ̀ ń kígbe pé, “Oluwa ṣàánú wa, ọmọ Dafidi.”

32. Jesu bá dúró, ó pè wọ́n, ó ní, “Kí ni ẹ fẹ́ kí n ṣe fun yín?”

33. Wọ́n dá a lóhùn pé, “Oluwa, a fẹ́ kí ojú wa là ni.”

Ka pipe ipin Matiu 20