Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Maku 4:8-22 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Irúgbìn mìíràn bọ́ sí ilẹ̀ tí ó dára, wọ́n yọ sókè, wọ́n ń dàgbà, wọ́n sì ń so èso, òmíràn ọgbọ̀n, òmíràn ọgọta, òmíràn ọgọrun-un.”

9. Lẹ́yìn náà Jesu ní, “Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́ràn, kí ó gbọ́!”

10. Nígbà tí ó ku òun nìkan, àwọn tí ó wà pẹlu rẹ̀ ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila bèèrè ìtumọ̀ àwọn òwe tí ó fi ń sọ̀rọ̀.

11. Ó bá sọ fún wọn pé, “Ẹ̀yin ni a fi fún láti mọ ohun ìjìnlẹ̀ ìjọba Ọlọrun, ṣugbọn bí òwe bí òwe ni fún àwọn ẹlòmíràn tí ó wà lóde.

12. Kí wọn baà lè la ojú sílẹ̀ṣugbọn kí wọn má ríran;kí wọn gbọ́ títíṣugbọn kí òye má yé wọn;kí wọn má baà ronupiwada,kí á má baà dáríjì wọ́n.”

13. Ó wá wí fún wọn pé, “Nígbà tí òwe yìí kò ye yín, báwo ni ẹ óo ti ṣe mọ gbogbo àwọn òwe ìyókù?

14. Afunrugbin fúnrúgbìn ọ̀rọ̀ ìròyìn ayọ̀.

15. Àwọn wọnyi ni ti ẹ̀bá ọ̀nà, níbi tí a fúnrúgbìn ọ̀rọ̀ náà sí: àwọn tí ó jẹ́ pé, lẹsẹkẹsẹ tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, Satani wá, ó mú ọ̀rọ̀ tí a ti fún sinu ọkàn wọn lọ.

16. Bákan náà ni àwọn ẹlòmíràn dàbí irúgbìn tí a fún sórí òkúta, nígbà tí wọn bá gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, wọn á fi inú dídùn gbà á.

17. Ṣugbọn nítorí tí wọn kò ní gbòǹgbò ninu ara wọn, àkókò díẹ̀ ni ọ̀rọ̀ náà gbé ninu wọn. Nígbà tí ìyọnu tabi inúnibíni bá dé nítorí ọ̀rọ̀ náà lẹsẹkẹsẹ wọn á kùnà.

18. Àwọn mìíràn dàbí irúgbìn tí a fún sórí ilẹ̀ ẹlẹ́gùn-ún, wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ náà,

19. ṣugbọn ayé, ati ìtànjẹ ọrọ̀, ati ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ mìíràn gba ọkàn wọn, ó sì fún ọ̀rọ̀ náà pa, kò sì so èso.

20. Àwọn mìíràn dàbí irúgbìn tí a fún sórí ilẹ̀ rere. Àwọn yìí ni ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, tí wọ́n gbà á, tí wọ́n sì so èso, òmíràn ọgbọọgbọn, òmíràn ọgọọgọta, òmíran ọgọọgọrun-un.”

21. Jesu bi wọ́n pé, “Eniyan a máa gbé fìtílà wọlé kí ó fi igbá bò ó, tabi kí ó gbé e sí abẹ́ ibùsùn? Mo ṣebí lórí ọ̀pá fìtílà ni à ń gbé e kà.

22. Nítorí kò sí ohun tí a fi pamọ́ tí a kò ní gbé jáde, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ohun ìkọ̀kọ̀ kan tí a kò ní yọ sí gbangba.

Ka pipe ipin Maku 4