Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Maku 2:1-18 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀, Jesu tún lọ sí Kapanaumu, àwọn eniyan gbọ́ pé ó wà ninu ilé kan.

2. Ọ̀pọ̀ eniyan bá wá péjọ sibẹ, wọ́n pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi jẹ́ pé ati inú ilé, ati ẹnu ọ̀nà ni ó kún. Ó bá ń sọ̀rọ̀ ìyìn rere fún wọn.

3. Àwọn mẹrin kan ń gbé arọ kan bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀.

4. Nígbà tí wọn kò lè gbé e dé ọ̀dọ̀ rẹ̀ nítorí ọ̀pọ̀ eniyan, wọ́n dá òrùlé lu ní ọ̀kánkán ibi tí Jesu wà. Nígbà tí wọ́n ti dá a lu tán, wọ́n sọ ọkunrin arọ náà kalẹ̀ ti òun ti ibùsùn rẹ̀.

5. Nígbà tí Jesu rí igbagbọ wọn, ó wí fún arọ náà pé, “Ọmọ, a dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.”

6. Ṣugbọn àwọn amòfin kan jókòó níbẹ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kùn sinu pé,

7. “Kí ló dé tí eléyìí fi ń sọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀? Ó ń sọ̀rọ̀ àfojúdi sí Ọlọrun. Ta ni lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji ni bíkòṣe Ọlọrun nìkan?”

8. Ṣugbọn Jesu mọ̀ ninu ara rẹ̀ pé wọ́n ń ro èrò báyìí ninu ọkàn wọn. Ó wí fún wọn pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ń kùn sinu?

9. Èwo ni ó rọrùn jù: Láti wí fún arọ náà pé, ‘A dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́,’ tabi láti wí pé, ‘Dìde, gbé ibùsùn rẹ, kí o máa rìn?’

10. Ṣugbọn kí ẹ lè mọ̀ pé Ọmọ-Eniyan ní àṣẹ ní ayé láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji ni,” ó bá wí fún arọ náà pé,

11. “Mo wí fún ọ, dìde, gbé ibùsùn rẹ, kí o máa lọ sí ilé rẹ.”

12. Ọkunrin náà bá dìde lẹsẹkẹsẹ, ó gbé ibùsùn rẹ̀, ó bá jáde lọ lójú gbogbo wọn. Ẹnu ya gbogbo wọn, wọ́n sì ń yin Ọlọrun, wọ́n ní, “A kò rí èyí rí.”

13. Jesu tún jáde lọ sí ẹ̀bá òkun, gbogbo àwọn eniyan ń lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, ó bá ń kọ́ wọn.

14. Bí ó ti ń lọ, ó rí Lefi ọmọ Alfeu tí ó jókòó níbi tí ó ti ń gba owó-odè. Ó wí fún un pé, “Máa tẹ̀lé mi.” Lefi bá dìde, ó sì tẹ̀lé e.

15. Bí Jesu ti jókòó ní ilé Lefi, ọpọlọpọ àwọn agbowó-odè ati àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ń bá Jesu ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ jẹun, nítorí wọ́n pọ̀ tí wọn ń tẹ̀lé e.

16. Nígbà tí àwọn amòfin ninu àwọn Farisi rí i tí ó ń bá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ati àwọn agbowó-odè jẹun, wọ́n bi àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ léèrè pé, “Kí ló dé tí ó fi ń bá àwọn agbowó-odè ati àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ jẹun?”

17. Nígbà tí Jesu gbọ́, ó wí fún wọn pé, “Àwọn tí ara wọn le kò nílò oníṣègùn bíkòṣe àwọn tí ara wọn kò dá: èmi kò wá láti pe àwọn olódodo bíkòṣe àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.”

18. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu ati àwọn Farisi ń gbààwẹ̀ ní àkókò kan. Àwọn kan wá, wọ́n ń bi Jesu pé, “Kí ló dé tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn àwọn Farisi a máa gbààwẹ̀ ṣugbọn àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tìrẹ kì í gbààwẹ̀?”

Ka pipe ipin Maku 2