Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Luku 2:13-24 BIBELI MIMỌ (BM)

13. Lójijì ọpọlọpọ àwọn ogun ọ̀run yọ pẹlu angẹli náà, wọ́n ń yin Ọlọrun pé,

14. “Ògo fún Ọlọrun lókè ọ̀run,alaafia ní ayé fún àwọn tí inú Ọlọrun dùn sí.”

15. Lẹ́yìn tí àwọn angẹli náà ti pada kúrò lọ́dọ̀ wọn lọ sí ọ̀run, àwọn olùṣọ́-aguntan ń sọ láàrin ara wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí á lọ sí Bẹtilẹhẹmu tààrà, kí á lè rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, tí Oluwa bùn wá gbọ́.”

16. Wọ́n bá yára lọ. Wọ́n wá Maria kàn ati Josẹfu ati ọmọ-ọwọ́ náà tí a tẹ́ sí ibùjẹ ẹran.

17. Nígbà tí wọ́n rí i, wọ́n sọ ohun gbogbo tí a ti sọ fún wọn nípa ọmọ náà.

18. Ẹnu sì ya gbogbo àwọn tí ó gbọ́ ohun tí àwọn olùṣọ́-aguntan náà sọ fún wọn.

19. Ṣugbọn Maria ń ṣe akiyesi gbogbo ọ̀rọ̀ wọnyi, ó ń dà wọ́n rò ní ọkàn rẹ̀.

20. Àwọn olùṣọ́-aguntan náà pada síbi iṣẹ́ wọn, wọ́n ń fi ògo ati ìyìn fún Ọlọrun fún gbogbo nǹkan tí wọ́n gbọ́, ati àwọn nǹkan tí wọ́n rí gẹ́gẹ́ bí angẹli náà ti sọ fún wọn.

21. Nígbà tí ọjọ́ kẹjọ pé láti kọ ọmọ náà ní ilà-abẹ́, wọ́n sọ orúkọ rẹ̀ ní Jesu, gẹ́gẹ́ bí angẹli ti wí, kí ìyá rẹ̀ tó lóyún rẹ̀.

22. Nígbà tí ó tó àkókò fún àwọn òbí rẹ̀ láti ṣe àṣà ìwẹ̀mọ́ gẹ́gẹ́ bí òfin Mose, wọ́n gbé ọmọ náà lọ sí Jerusalẹmu láti fi í fún Oluwa.

23. Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ ninu òfin Oluwa pé, “Gbogbo àkọ́bí lọkunrin ni a óo pè ní mímọ́ fún Oluwa.”

24. Wọ́n tún lọ láti rú ẹbọ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà ninu òfin Oluwa: pẹlu àdàbà meji, tabi ọmọ ẹyẹlé meji.

Ka pipe ipin Luku 2