Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Luku 16:10-25 BIBELI MIMỌ (BM)

10. Ẹni tí ó bá ṣe olóòótọ́ ninu nǹkan kékeré yóo ṣe olóòótọ́ ninu nǹkan ńlá.

11. Nítorí náà bí ẹ kò bá ṣe é gbẹ́kẹ̀lé nípa nǹkan owó ti ayé yìí, ta ni yóo fi dúkìá tòótọ́ sí ìkáwọ́ yín?

12. Bí ẹ kò bá ṣe é gbẹ́kẹ̀lé nípa ohun tí ó jẹ́ ti ẹlòmíràn, ta ni yóo fun yín ní ohun tí ó jẹ́ ti ẹ̀yin fúnra yín?

13. “Kò sí ọmọ-ọ̀dọ̀ kan tí ó lè sin oluwa meji. Nítorí ọ̀kan ni yóo ṣe: ninu kí ó kórìíra ọ̀kan, kí ó fẹ́ràn ekeji, tabi kí ó fara mọ́ ọ̀kan, kí ó má sì ka ekeji sí. Ẹ kò lè sin Ọlọrun, kí ẹ tún sin owó.”

14. Nígbà tí àwọn Farisi tí wọ́n fẹ́ràn owó gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí, ńṣe ni wọ́n ń yínmú sí i.

15. Ó wá sọ fún wọn pé, “Ẹ̀yin ni ẹ̀ ń dá ara yín láre lójú eniyan, ṣugbọn Ọlọrun mọ ọkàn yín. Ohun tí eniyan ń gbé gẹ̀gẹ̀, ohun ẹ̀gbin ni lójú Ọlọrun.

16. “Ìwé òfin Mose ati ìwé àwọn wolii ni ó wà fún ìlànà títí di àkókò Johanu. Láti ìgbà náà ni a ti ń waasu ìyìn rere ti ìjọba Ọlọrun. Pẹlu ipá sì ni olukuluku fi ń wọ̀ ọ́.

17. Ó rọrùn kí ọ̀run ati ayé kọjá ju pé kí kínńkínní ninu òfin kí ó má ṣẹ lọ.

18. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ iyawo rẹ̀ sílẹ̀ tí ó gbé iyawo mìíràn ṣe àgbèrè. Bí ẹnìkan bá sì gbé obinrin tí a ti kọ̀ sílẹ̀ ní iyawo òun náà ṣe àgbèrè.

19. “Ọkunrin kán wà tí ó lówó. Aṣọ àlàárì ati àwọn aṣọ olówó iyebíye mìíràn ni ó máa ń wọ̀. Oúnjẹ àdídùn ni ó máa ń jẹ, lojoojumọ ni ó máa ń se àsè.

20. Talaka kan wà tí ó ń jẹ́ Lasaru, tíí máa ń jókòó lẹ́nu ọ̀nà ilé ọlọ́rọ̀ yìí. Gbogbo ara Lasaru jẹ́ kìkì egbò.

21. Inú rẹ̀ ìbá dùn láti máa jẹ ẹ̀rúnrún tí ó ń bọ́ sílẹ̀ láti orí tabili olówó yìí. Pẹlu bẹ́ẹ̀ náà, ajá a máa wá lá egbò ara rẹ̀.

22. “Nígbà tí ó yá, talaka yìí kú, àwọn angẹli bá gbé e lọ sọ́dọ̀ Abrahamu. Olówó náà kú, a sì sin ín.

23. Ní ipò òkú ni ó rí ara rẹ̀, tí ó ń joró. Ó wá rí Abrahamu ní òkèèrè pẹlu Lasaru ní ọ̀dọ̀ rẹ̀.

24. Ó bá pè é, ó ní, ‘Abrahamu, Baba, ṣàánú mi. Rán Lasaru kí ó ti ìka rẹ̀ bọ omi, kí ó wá kán an sí mi láhọ́n, nítorí mò ń jẹ ìrora ninu iná yìí.’

25. “Ṣugbọn Abrahamu dá a lóhùn pé, ‘Ọmọ, ranti pé nígbà tí o wà láyé, kìkì ohun rere ni o gbà, nígbà tí ó jẹ́ pé nǹkan burúkú ni Lasaru gbà. Nisinsinyii, ìdẹ̀ra ti dé bá Lasaru nígbà tí ìwọ ń jẹ̀rora.

Ka pipe ipin Luku 16