Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Kinni 6:1-13 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Lẹ́yìn tí àpótí OLUWA ti wà ní ilẹ̀ Filistini fún oṣù meje,

2. àwọn ará ilẹ̀ náà pe àwọn babalóòṣà wọn ati àwọn adáhunṣe wọn jọ, wọ́n bi wọ́n pé, “Báwo ni kí á ti ṣe àpótí OLUWA? Bí a óo bá dá a pada sí ibi tí wọ́n ti gbé e wá, kí ni kí á fi ranṣẹ pẹlu rẹ̀?”

3. Wọ́n dá wọn lóhùn pé, “Bí ẹ óo bá dá àpótí Ọlọrun Israẹli pada, ẹ gbọdọ̀ dá a pada pẹlu ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi, àpótí ẹ̀rí náà kò gbọdọ̀ pada lọ lásán, láìsí nǹkan ètùtù. Bẹ́ẹ̀ ni ara yín yóo ṣe yá, ẹ óo sì mọ ìdí tí Ọlọrun fi ń jẹ yín níyà.”

4. Àwọn eniyan náà bi wọ́n pé, “Kí ni kí á fi ranṣẹ gẹ́gẹ́ bí nǹkan ètùtù?”Àwọn babalóòṣà dá wọn lóhùn pé, “Ẹ fi wúrà yá ère kókó ọlọ́yún marun-un, ati ti èkúté marun-un, kí ẹ fi ranṣẹ. Kókó ọlọ́yún wúrà marun-un ati èkúté marun-un dúró fún àwọn ọba Filistini maraarun. Nítorí àjàkálẹ̀ àrùn kan náà ni ó kọlu gbogbo yín ati àwọn ọba yín maraarun.

5. Ẹ gbọdọ̀ fi wúrà yá ère kókó ọlọ́yún yín ati ti èkúté tí ń ba ilẹ̀ yín jẹ́, kí ẹ sì fi ògo fún Ọlọrun Israẹli bóyá ó lè dáwọ́ ìjìyà rẹ̀ dúró lórí ẹ̀yin ati oriṣa yín, ati ilẹ̀ yín.

6. Kí ló dé tí ẹ fi fẹ́ ṣe oríkunkun, bí ọba ilẹ̀ Ijipti ati àwọn ará Ijipti. Ẹ ranti bí Ọlọrun ti fi wọ́n ṣe ẹlẹ́yà títí tí wọ́n fi jẹ́ kí àwọn ọmọ Israẹli lọ. Wọ́n kúkú lọ!

7. Nítorí náà ẹ kan kẹ̀kẹ́ ẹrù tuntun kan, kí ẹ sì tọ́jú abo mààlúù meji tí ń fún ọmọ lọ́mú tí ẹnikẹ́ni kò sì so àjàgà mọ́ lọ́rùn rí, ẹ so kẹ̀kẹ́ ẹrù náà mọ́ wọn lọ́rùn, kí ẹ sì lé àwọn ọmọ wọn pada sílé.

8. Ẹ gbé àpótí OLUWA lé orí kẹ̀kẹ́ ẹrù náà. Ẹ kó àwọn kókó ọlọ́yún ati àwọn èkúté tí ẹ fi wúrà ṣe, tí ẹ fẹ́ fi ranṣẹ gẹ́gẹ́ bí nǹkan ètùtù sinu àpótí kan, kí ẹ wá gbé e sí ẹ̀gbẹ́ àpótí OLUWA. Lẹ́yìn náà, ẹ ti kẹ̀kẹ́ ẹrù yìí sójú ọ̀nà, kí ẹ sì jẹ́ kí ó máa lọ fúnrarẹ̀.

9. Ẹ máa kíyèsí i bí ó bá ti ń lọ. Bí ó bá doríkọ ọ̀nà ìlú Beti Ṣemeṣi, a jẹ́ pé Ọlọrun àwọn ọmọ Israẹli ni ó kó gbogbo àjálù yìí bá wa. Bí kò bá doríkọ ibẹ̀, a óo mọ̀ pé kì í ṣe òun ló rán àjálù náà sí wa, a jẹ́ pé ó kàn dé bá wa ni.”

10. Àwọn eniyan náà ṣe bí àwọn babalóòṣà ti wí. Wọ́n mú mààlúù meji tí wọn ń fún ọmọ lọ́mú lọ́wọ́, wọ́n so kẹ̀kẹ́ ẹrù náà mọ́ wọn lọ́rùn, wọ́n sì ti àwọn ọmọ wọn mọ́lé.

11. Wọ́n gbé àpótí OLUWA sinu kẹ̀kẹ́ ẹrù náà, pẹlu àpótí tí wọ́n kó àwọn èkúté wúrà ati kókó ọlọ́yún wúrà náà sí.

12. Àwọn mààlúù yìí bá doríkọ ọ̀nà Beti Ṣemeṣi, wọ́n ń lọ tààrà láì yà sọ́tùn-ún tabi sósì. Wọ́n ń ké bí wọ́n ti ń lọ. Àwọn ọba Filistini maraarun tẹ̀lé wọn títí dé odi Beti Ṣemeṣi.

13. Àwọn ará ìlú Beti ṣemeṣi ń kórè ọkà lọ́wọ́ ní àfonífojì náà, bí wọ́n ti gbójú sókè, wọ́n rí àpótí ẹ̀rí. Inú wọn dùn pupọ pupọ bí wọ́n ti rí i.

Ka pipe ipin Samuẹli Kinni 6