Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Kinni 20:18-29 BIBELI MIMỌ (BM)

18. Lẹ́yìn náà, Jonatani sọ fún Dafidi pé, “Ọ̀la ni ọjọ́ àjọ̀dún oṣù tuntun, àwọn eniyan yóo sì mọ̀ bí o kò bá wá síbi oúnjẹ nítorí ààyè rẹ yóo ṣófo.

19. Bí wọn kò bá rí ọ ní ọjọ́ keji, wọn yóo mọ̀ dájú pé o kò sí láàrin wọn. Nítorí náà, lọ sí ibi tí o farapamọ́ sí ní ìjelòó, kí o sì farapamọ́ sẹ́yìn àwọn òkúta ọ̀hún nnì.

20. N óo sì ta ọfà mẹta sí ìhà ibẹ̀ bí ẹni pé mo ta wọ́n sí àmì kan.

21. N óo rán ọmọkunrin kan láti wá àwọn ọfà náà. Bí mo bá sọ fún un pé, ‘Wò ó àwọn ọfà náà wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ,’ kí o jáde wá, nítorí bí OLUWA tí ń bẹ, kò sí ewu kankan fún ọ.

22. Ṣugbọn bí mo bá sọ fún un pé, ‘Wo àwọn ọfà náà níwájú rẹ,’ máa bá tìrẹ lọ nítorí OLUWA ni ó fẹ́ kí o lọ.

23. Nípa ọ̀rọ̀ tí èmi pẹlu rẹ jọ sọ, ranti pé OLUWA wà láàrin wa laelae.”

24. Dafidi farapamọ́ ninu pápá, ní ọjọ́ àjọ̀dún oṣù tuntun, Saulu ọba jókòó láti jẹun.

25. Ọba jókòó níbi tí ó máa ń jókòó sí ní ẹ̀gbẹ́ ògiri, Jonatani jókòó ní iwájú rẹ̀. Abineri sì jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ Saulu. Ṣugbọn ààyè Dafidi ṣófo.

26. Sibẹ Saulu kò sọ nǹkankan nítorí pé ó rò pé bóyá nǹkankan ti ṣẹlẹ̀ sí Dafidi, tí ó sì sọ ọ́ di aláìmọ́ ni.

27. Ní ọjọ́ keji àjọ̀dún oṣù tuntun, ìjókòó Dafidi tún ṣófo. Nígbà náà ni Saulu bèèrè lọ́wọ́ Jonatani pé, “Kí ló dé tí ọmọ Jese kò wá sí ibi oúnjẹ lánàá ati lónìí?”

28. Jonatani dáhùn pé, “Ó gbààyè lọ́wọ́ mi láti lọ sí Bẹtilẹhẹmu.

29. Ó sọ pé, àwọn ẹ̀gbọ́n òun ti pa á láṣẹ fún òun láti wá sí ibi àjọ̀dún ẹbọ ọdọọdún ti ìdílé wọn. Ó sì tọrọ ààyè lọ́wọ́ mi pé òun fẹ́ wà pẹlu àwọn ìdílé òun ní àkókò àjọ̀dún náà. Òun ni kò fi lè wá síbi àsè ọba.”

Ka pipe ipin Samuẹli Kinni 20