N óo rán ọmọkunrin kan láti wá àwọn ọfà náà. Bí mo bá sọ fún un pé, ‘Wò ó àwọn ọfà náà wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ,’ kí o jáde wá, nítorí bí OLUWA tí ń bẹ, kò sí ewu kankan fún ọ.