Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Kinni 12:5-13 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Samuẹli dáhùn pé, “OLUWA ati ọba, ẹni àmì òróró rẹ̀ ni ẹlẹ́rìí lónìí pé, ẹ gbà pé ọwọ́ mi mọ́ patapata.”Àwọn eniyan náà dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, OLUWA ni ẹlẹri wa.”

6. Samuẹli tún sọ fún wọn pé, “OLUWA tí ó yan Mose ati Aaroni, tí ó kó àwọn baba ńlá yín jáde wá láti ilẹ̀ Ijipti ni ẹlẹ́rìí.

7. Ẹ dúró jẹ́ẹ́, n óo sì fi ẹ̀sùn kàn yín níwájú OLUWA n óo ran yín létí gbogbo àwọn iṣẹ́ ìyanu ńlá tí OLUWA ṣe láti gba àwọn baba ńlá yín kalẹ̀.

8. Nígbà tí Jakọbu ati ìdílé rẹ̀ lọ sí ilẹ̀ Ijipti, tí àwọn ará Ijipti ń ni wọ́n lára, àwọn baba ńlá yín kígbe pe OLUWA fún ìrànlọ́wọ́, OLUWA sì rán Mose ati Aaroni, wọ́n kó wọn jáde kúrò ní Ijipti. Ó sì mú kí wọ́n máa gbé orí ilẹ̀ yìí.

9. Ṣugbọn wọ́n gbàgbé OLUWA Ọlọrun wọn. Wọ́n jagun, OLUWA sì fi wọ́n lé Sisera, olórí ogun Jabini ọba Hasori lọ́wọ́, àwọn ará Filistia ati ọba Moabu náà sì ṣẹgun wọn.

10. Lẹ́yìn náà, àwọn baba ńlá yín kígbe pe OLUWA fún ìrànlọ́wọ́. Wọ́n ní, ‘A ti ṣẹ̀, nítorí pé a ti kọ OLUWA sílẹ̀, a sì ń sin oriṣa Baali, ati ti Aṣitarotu. Nisinsinyii, gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa, a óo sì máa sìn ọ́.’

11. OLUWA bá rán Jerubaali ati Baraki, ati Jẹfuta ati èmi, Samuẹli, láti gbà yín lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá yín káàkiri, ó sì jẹ́ kí ẹ wà ní alaafia.

12. Ṣugbọn nígbà tí ẹ rí i pé Nahaṣi, ọba Amoni fẹ́ gbé ogun tì yín, ẹ kọ OLUWA lọ́ba, ẹ wí fún mi pé, ẹ fẹ́ ọba tí yóo jẹ́ alákòóso yín.

13. “Ọba tí ẹ bèèrè fún náà nìyí, ẹ̀yin ni ẹ bèèrè rẹ̀, OLUWA sì ti fun yín nisinsinyii.

Ka pipe ipin Samuẹli Kinni 12