Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Kinni 11:1-8 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Nahaṣi, ọba Amoni, kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀, wọ́n lọ gbógun ti ìlú Jabeṣi Gileadi. Àwọn ará Jabeṣi bá sọ fún Nahaṣi pé, “Jẹ́ kí á jọ dá majẹmu, a óo sì máa sìn ọ́.”

2. Nahaṣi dá wọn lóhùn pé, “Ohun tí mo fi lè ba yín dá majẹmu ni pé, kí n yọ ojú ọ̀tún ẹnìkọ̀ọ̀kan yín, kí ó lè jẹ́ ìtìjú fún gbogbo Israẹli.”

3. Àwọn àgbààgbà Jabeṣi dáhùn pé, “Fún wa ní ọjọ́ meje, kí á lè ranṣẹ jákèjádò ilẹ̀ Israẹli. Bí kò bá sí ẹni tí yóo gbà wá, a óo jọ̀wọ́ ara wa fún ọ.”

4. Nígbà tí àwọn oníṣẹ́ náà dé Gibea, níbi tí Saulu ń gbé, wọ́n ròyìn fún àwọn ará ìlú náà, gbogbo wọn sì pohùnréré ẹkún.

5. Ní àkókò yìí gan-an ni Saulu ń ti oko rẹ̀ bọ̀, pẹlu àwọn akọ mààlúù rẹ̀. Ó bèèrè pé, “Kí ló ṣẹlẹ̀ tí gbogbo eniyan fi ń sọkún?” Wọ́n bá sọ ohun tí àwọn ará Jabeṣi sọ fún un.

6. Nigba tí Saulu gbọ́ èyí, ẹ̀mí Ọlọrun bà lé Saulu inú sì bí i gidigidi.

7. Ó mú akọ mààlúù meji, ó gé wọn sí wẹ́wẹ́, ó fi wọ́n ranṣẹ jákèjádò ilẹ̀ Israẹli, pẹlu ìkìlọ̀ pé, “Ẹnikẹ́ni tí kò bá tẹ̀lé Saulu ati Samuẹli lọ sójú ogun, bí a óo ti ṣe àwọn akọ mààlúù rẹ̀ nìyí.”Ìbẹ̀rù OLUWA mú àwọn ọmọ Israẹli, gbogbo wọn patapata jáde láì ku ẹnìkan.

8. Saulu bá kó wọn jọ ní Beseki. Ọ̀kẹ́ mẹẹdogun (300,000) ni àwọn tí wọ́n wá láti ilẹ̀ Israẹli, àwọn tí wọ́n wá láti Juda sì jẹ́ ẹgbaa mẹẹdogun (30,000).

Ka pipe ipin Samuẹli Kinni 11