Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Keji 7:14-29 BIBELI MIMỌ (BM)

14. N óo jẹ́ baba fún un, yóo sì jẹ́ ọmọ mi. Bí ó bá ṣẹ̀, n óo bá a wí, n óo sì jẹ ẹ́ níyà, bí baba ti í ṣe sí ọmọ rẹ̀.

15. Ṣugbọn n kò ní káwọ́ ìfẹ́ ńlá mi kúrò lára rẹ̀, bí mo ti ká a kúrò lára Saulu, tí mo sì yọ ọ́ lóyè, kí n tó fi í jọba.

16. Ìran rẹ kò ní parun, arọmọdọmọ rẹ ni yóo sì máa jọba títí ayé, ìjọba rẹ̀ yóo sì wà títí lae.’ ”

17. Natani bá tọ Dafidi lọ, ó sì sọ gbogbo nǹkan tí OLUWA fi hàn án fún un.

18. Dafidi ọba bá wọlé, ó jókòó níwájú OLUWA, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gbadura pé, “Ìwọ OLUWA Ọlọrun! Kí ni mo jẹ́, kí ni ilé mi jámọ́ tí o fi gbé mi dé ipò yìí?

19. Sibẹsibẹ, kò jẹ́ nǹkankan lójú rẹ, OLUWA Ọlọrun, o ti ṣèlérí fún èmi iranṣẹ rẹ nípa arọmọdọmọ mi, nípa ọjọ́ iwájú, o sì ti fihàn.

20. Kí ni mo tún lè sọ? O ṣá ti mọ̀ mí, èmi iranṣẹ rẹ, OLUWA Ọlọrun!

21. Nítorí ìlérí ati ìfẹ́ ọkàn rẹ ni o fi ṣe gbogbo nǹkan ńlá wọnyi, kí iranṣẹ rẹ lè mọ̀ nípa wọn.

22. OLUWA Ọlọrun, o tóbi gan-an! Kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ, bẹ́ẹ̀ ni kò sí Ọlọrun mìíràn lẹ́yìn rẹ, nítorí gbogbo ohun tí a ti fi etí wa gbọ́.

23. Kò sí orílẹ̀-èdè mìíràn ní gbogbo ayé, tí ó dàbí Israẹli, tí o yọ kúrò ní oko ẹrú láti fi wọ́n ṣe eniyan rẹ. O ti mú kí òkìkí Israẹli kàn nípa àwọn nǹkan ńláńlá, ati nǹkan ìyanu tí o ti ṣe fún wọn, nípa lílé àwọn eniyan orílẹ̀-èdè mìíràn jáde tàwọn ti oriṣa wọn, bí àwọn eniyan rẹ ti ń tẹ̀síwájú.

24. O ti yan àwọn ọmọ Israẹli fún ara rẹ, láti jẹ́ eniyan rẹ, o sì ti di Ọlọrun wọn títí lae.

25. “Ǹjẹ́ nisinsinyii, OLUWA Ọlọrun, jẹ́ kí ìlérí tí o ṣe nípa èmi ati arọmọdọmọ mi ṣẹ nígbà gbogbo, sì ṣe ohun tí o ti ṣèlérí pé o óo ṣe.

26. Orúkọ rẹ yóo sì lókìkí títí lae, gbogbo eniyan ni yóo sì máa wí títí lae pé, OLUWA àwọn ọmọ ogun ni Ọlọrun Israẹli. O óo sì mú kí arọmọdọmọ mi wà níwájú rẹ títí laelae.

27. OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli, pẹlu ìgboyà ni mo fi gbadura mi yìí sí ọ, nítorí pé o ti fi gbogbo nǹkan wọnyi han èmi iranṣẹ rẹ, o sì ti ṣèlérí pé o óo sọ ìdílé mi di ìdílé ńlá.

28. “Ǹjẹ́ nisinsinyii, OLUWA Ọlọrun, ìwọ nìkan ni Ọlọ́run, òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ, o sì ti ṣèlérí ohun rere yìí fún iranṣẹ rẹ.

29. Mò ń bẹ̀bẹ̀ pé kí o bukun arọmọdọmọ mi, kí wọ́n lè máa bá ojurere rẹ pàdé nígbà gbogbo. Ìwọ OLUWA Ọlọrun ni o ṣèlérí yìí, ibukun rẹ yóo sì máa wà lórí arọmọdọmọ mi títí laelae.”

Ka pipe ipin Samuẹli Keji 7