Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Keji 15:13-21 BIBELI MIMỌ (BM)

13. Oníṣẹ́ kan wá ròyìn fún Dafidi pé, “Ọkàn gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ti ṣí sí ọ̀dọ̀ Absalomu.”

14. Dafidi bá sọ fún gbogbo àwọn iranṣẹ rẹ̀, tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ ní Jerusalẹmu pé, “A gbọdọ̀ sá lọ lẹsẹkẹsẹ, bí a kò bá fẹ́ bọ́ sọ́wọ́ Absalomu. Ẹ ṣe gírí, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, yóo bá wa, yóo ṣẹgun wa, yóo sì pa ìlú yìí run.”

15. Àwọn iranṣẹ rẹ̀ dáhùn pé, “Kabiyesi, ohunkohun tí o bá wí ni a óo ṣe.”

16. Ọba bá jáde kúrò ní ìlú, gbogbo ìdílé rẹ̀, ati àwọn iranṣẹ rẹ̀ sì tẹ̀lé e. Ṣugbọn ọba fi mẹ́wàá ninu àwọn obinrin rẹ̀ sílẹ̀ láti máa bojútó ààfin.

17. Bí ọba ati gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ ti ń jáde kúrò ní ìlú, wọ́n dúró níbi ilé tí ó wà ní ìpẹ̀kun ìlú.

18. Gbogbo àwọn iranṣẹ rẹ̀ sì ń tò kọjá níwájú rẹ̀; àwọn ẹgbẹta (600) ọmọ ogun tí wọ́n tẹ̀lé e láti Gati náà tò kọjá níwájú rẹ̀.

19. Ọba bá kọjú sí Itai ará Gati, ó sì bi í pé, “Kí ló dé tí o fi ń bá wa lọ? Pada, kí o lọ dúró ti ọba, àlejò ni ọ́, sísá ni o sá kúrò ní ìlú rẹ wá síhìn-ín.

20. Kò sì tíì pẹ́ pupọ tí o dé, kí ló dé tí o fi fẹ́ máa bá mi káàkiri ninu ìrìnkèrindò mi? Èmi gan-an nìyí, n kò tíì mọ ibi tí mò ń lọ. Pada kí àwọn ará ìlú rẹ gbogbo sì máa bá ọ lọ. OLUWA yóo fẹ́ràn ìwọ náà, yóo sì dúró tì ọ́.”

21. Ṣugbọn Itai dáhùn pé, “Kabiyesi, mo fi OLUWA búra, bí ẹ̀mí oluwa mi ọba tí ń bẹ láàyè, pé, ibikíbi tí o bá ń lọ ni n óo máa bá ọ lọ, kì báà tilẹ̀ já sí ikú.”

Ka pipe ipin Samuẹli Keji 15