Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Keji 12:13-22 BIBELI MIMỌ (BM)

13. Dafidi bá dáhùn pé, “Mo ti ṣẹ̀ sí OLUWA.”Natani dá a lóhùn pé, “OLUWA ti dáríjì ọ́, o kò sì ní kú.

14. Ṣugbọn nítorí pé ohun tí o ṣe yìí jẹ́ àfojúdi sí OLUWA, ọmọ tí ó bí fún ọ yóo kú.”

15. Natani bá lọ sí ilé rẹ̀.OLUWA fi àìsàn ṣe ọmọ tí aya Uraya bí fún Dafidi.

16. Dafidi bá ń gbadura sí Ọlọrun pé kí ara ọmọ náà lè yá, ó ń gbààwẹ̀, ó sì ń sùn lórí ilẹ̀ lásán ní alaalẹ́.

17. Àwọn àgbààgbà tí wọ́n wà ninu ilé rẹ̀ rọ̀ ọ́, pé kí ó dìde nílẹ̀, ṣugbọn ó kọ̀, kò sì bá wọn jẹ nǹkankan.

18. Ní ọjọ́ keje, ọmọ náà kú, ẹ̀rù sì ba àwọn iranṣẹ Dafidi láti sọ fún un pé ọmọ ti kú. Wọ́n ní, “Ìgbà tí ọmọ yìí wà láàyè, a bá Dafidi sọ̀rọ̀, kò dá wa lóhùn. Báwo ni a ṣe fẹ́ sọ fún un pé ọmọ ti kú? Ó lè pa ara rẹ̀ lára.”

19. Nígbà tí Dafidi rí i pé wọ́n ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, ó fura pé ọmọ ti kú. Ó bèèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ṣé ọmọ ti kú ni?”Wọ́n dá a lóhùn pé, “Ó ti kú.”

20. Dafidi bá dìde kúrò ní ilẹ̀, ó wẹ̀, ó fi òróró pa ara rẹ̀, ó pààrọ̀ aṣọ rẹ̀, ó sì lọ sí ilé OLUWA láti jọ́sìn. Lẹ́yìn náà, ó pada sí ilé rẹ̀, ó bèèrè fún oúnjẹ, wọ́n gbé e fún un, ó sì jẹ ẹ́.

21. Àwọn iranṣẹ rẹ̀ bi í pé, “Kabiyesi, ọ̀rọ̀ yìí rú wa lójú, kí ni ohun tí ò ń ṣe yìí? Nígbà tí ọmọ yìí wà láàyè, ò ń gbààwẹ̀, ò ń sọkún nítorí rẹ̀. Ṣugbọn gbàrà tí ó kú tán, o dìde o sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹun!”

22. Dafidi dá wọn lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, nígbà tí ó wà láàyè, mo gbààwẹ̀, mo sì sọkún, pé bóyá OLUWA yóo ṣàánú mi, kí ó má kú.

Ka pipe ipin Samuẹli Keji 12