Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lefitiku 8:17-32 BIBELI MIMỌ (BM)

17. Ṣugbọn ó dáná sun ara ẹran akọ mààlúù náà, ati awọ rẹ̀, ati ìgbẹ́ rẹ̀ lẹ́yìn ibùdó náà, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un.

18. Lẹ́yìn náà, Mose fa àgbò ẹbọ sísun kalẹ̀, Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin sì gbé ọwọ́ wọn lé e lórí.

19. Lẹ́yìn náà, Mose pa á, ó da ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sórí pẹpẹ yípo.

20. Wọ́n gé ẹran àgbò náà sí wẹ́wẹ́, ó sun gbogbo rẹ̀ pẹlu orí rẹ̀ ati ọ̀rá rẹ̀ lórí pẹpẹ.

21. Nígbà tí ó fọ nǹkan inú rẹ̀ ati ẹsẹ̀ rẹ̀, ó fi gbogbo rẹ̀ rú ẹbọ sísun, ẹbọ olóòórùn dídùn tí a fi iná sun sí OLUWA, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose.

22. Lẹ́yìn náà, ó fa àgbò keji kalẹ̀, èyí tí í ṣe àgbò ìyàsímímọ́. Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ gbé ọwọ́ wọn lé e lórí.

23. Lẹ́yìn náà Mose pa á, ó tọ́ ninu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ó fi kan etí ọ̀tún Aaroni, ati àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, ati àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún rẹ̀.

24. Wọ́n mú àwọn ọmọ Aaroni náà jáde, Mose tọ́ ninu ẹ̀jẹ̀ náà, ó fi kan etí ọ̀tún wọn, ati àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún wọn, ati àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún wọn, ó sì da ẹ̀jẹ̀ yòókù sórí pẹpẹ yípo.

25. Lẹ́yìn náà, ó mú ọ̀rá àgbò náà, ati ọ̀rá ìrù rẹ̀, ati gbogbo ọ̀rá tí ó bo àwọn nǹkan inú rẹ̀, ati ẹ̀dọ̀ rẹ̀, ati kíndìnrín rẹ̀ mejeeji pẹlu ọ̀rá tí ó wà lára wọn, ati itan ọ̀tún rẹ̀.

26. Ó mú burẹdi dídùn kan tí kò ní ìwúkàrà ninu, ninu agbọ̀n burẹdi tí ó wà níwájú OLUWA, ati burẹdi olóròóró kan tí kò ní ìwúkàrà ninu ati burẹdi fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ kan, ó kó wọn lé orí ọ̀rá náà ati itan ọ̀tún àgbò náà.

27. Ó kó gbogbo rẹ̀ lé Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́, wọ́n sì fì wọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì níwájú OLUWA.

28. Lẹ́yìn náà, Mose gbà á kúrò lọ́wọ́ wọn, ó sun wọ́n lórí pẹpẹ, pẹlu ẹbọ sísun bí ẹbọ ìyàsímímọ́, ẹbọ olóòórùn dídùn, tí a fi iná sun sí OLÚWA.

29. Mose mú igẹ̀ àyà àgbò náà, ó fì í gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì níwájú OLUWA. Òun ni ìpín Mose ninu àgbò ìyàsímímọ́ yìí, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pa á láṣẹ fún un.

30. Lẹ́yìn náà, Mose mú ninu òróró ìyàsímímọ́, ati díẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀ tí ó wà lórí pẹpẹ, ó wọ́n ọn sí ara Aaroni ati aṣọ rẹ̀, ati sí ara àwọn ọmọ rẹ̀, ati aṣọ wọn. Bẹ́ẹ̀ ló ṣe ya Aaroni ati àwọn aṣọ rẹ̀ sí mímọ́, ati àwọn ọmọ rẹ̀, tàwọn taṣọ wọn.

31. Mose bá sọ fún Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin pé, “Ẹ lọ bọ ẹran àgbò náà lẹ́nu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ kí ẹ sì jẹ ẹ́ níbẹ̀, pẹlu burẹdi tí ó wà ninu agbọ̀n ọrẹ ẹbọ ìyàsímímọ́, gẹ́gẹ́ bí mo ti pa á láṣẹ pé: ‘Aaroni ati ọmọ rẹ̀ ni kí wọ́n máa jẹ ẹ́’.

32. Ohunkohun tí ó bá kù ninu ẹran ati burẹdi náà, ẹ dáná sun ún.

Ka pipe ipin Lefitiku 8