Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lefitiku 23:34-44 BIBELI MIMỌ (BM)

34. pé kí ó sọ fún àwọn eniyan Israẹli pé, “Láti ọjọ́ kẹẹdogun oṣù keje lọ, ẹ óo ṣe àjọ̀dún Àgọ́ fún OLUWA; ọjọ́ meje ni ẹ óo fi ṣe é.

35. Ìpéjọpọ̀ mímọ́ yóo wà ní ọjọ́ kinni, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ líle kankan ní ọjọ́ náà.

36. Ọjọ́ meje ni ẹ óo fi máa rú ẹbọ sísun sí OLUWA. Ní ọjọ́ kẹjọ, ẹ óo ní ìpéjọpọ̀ mímọ́, ẹ óo sì rú ẹbọ sísun sí OLUWA. Ìpéjọpọ̀ tí ó lọ́wọ̀ ni, nítorí náà, ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ líle kankan.

37. “Àwọn àjọ̀dún wọnyi ni OLUWA ti yà sọ́tọ̀; ẹ óo máa kéde wọn gẹ́gẹ́ bí àkókò ìpéjọpọ̀ mímọ́, láti máa rú ẹbọ tí a fi iná sun sí OLUWA, ẹbọ sísun, ati ẹbọ ohun jíjẹ; ati ẹbọ ohun mímu, olukuluku ní ọjọ́ tí a ti yàn fún wọn.

38. Àwọn ẹbọ wọnyi wà lọ́tọ̀ ní tiwọn, yàtọ̀ sí ti àwọn ọjọ́ ìsinmi fún OLUWA, ati àwọn ẹ̀bùn yín, ati àwọn ẹbọ ẹ̀jẹ́ yín, ati àwọn ọrẹ ẹbọ àtinúwá tí ẹ óo máa mú wá fún OLUWA.

39. “Lẹ́yìn tí ẹ bá ti kórè àwọn èso ilẹ̀ yín tán, láti ọjọ́ kẹẹdogun oṣù keje lọ, kí ẹ máa ṣe àjọ àjọ̀dún OLUWA fún ọjọ́ meje; ọjọ́ kinni ati ọjọ́ kẹjọ yóo jẹ́ ọjọ́ ìsinmi tí ó lọ́wọ̀.

40. Ní ọjọ́ kinni, ẹ óo mú ninu àwọn èso igi tí ó bá dára, ati imọ̀ ọ̀pẹ, ati ẹ̀ka igi tí ó ní ewé dáradára, ati ẹ̀ka igi wilo etí odò, kí ẹ sì bẹ̀rẹ̀ sí yọ̀ níwájú OLUWA Ọlọrun yín fún ọjọ́ meje.

41. Ọjọ́ meje láàrin ọdún kan ni ẹ óo máa fi ṣe àjọ̀dún fún OLUWA; Ìlànà títí lae ni èyí jẹ́ fún arọmọdọmọ yín. Ninu oṣù keje ọdún ni ẹ óo máa ṣe àjọ àjọ̀dún náà.

42. Inú àgọ́ ni ẹ óo máa gbé fún gbogbo ọjọ́ meje náà; gbogbo ẹni tí ó bá jẹ́ ọmọ Israẹli ni ó gbọdọ̀ gbé inú àgọ́,

43. kí àwọn arọmọdọmọ yín lè mọ̀ pé, inú àgọ́ ni mo mú kí àwọn ọmọ Israẹli máa gbé nígbà tí mo kó wọn jáde wá láti ilẹ̀ Ijipti. Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín.”

44. Bẹ́ẹ̀ ni Mose ṣe ṣàlàyé àwọn Àjọ àjọ̀dún tí OLUWA yàn, fún àwọn ọmọ Israẹli.

Ka pipe ipin Lefitiku 23