Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lefitiku 23:28-39 BIBELI MIMỌ (BM)

28. Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan ní ọjọ́ náà, nítorí ọjọ́ ètùtù ni, tí wọn yóo ṣe ètùtù fun yín níwájú OLUWA Ọlọrun yín.

29. Ẹnikẹ́ni tí kò bá gbààwẹ̀ ní ọjọ́ náà, a óo yọ ọ́ kúrò lára àwọn eniyan rẹ̀.

30. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣe iṣẹ́ kankan ní ọjọ́ náà, n óo pa á run láàrin àwọn eniyan rẹ̀.

31. Ẹ kò gbọdọ̀ ṣiṣẹ́ rárá, ìlànà ni ó jẹ́ títí lae fún ìrandíran yín, ní gbogbo ibùgbé yín.

32. Yóo jẹ́ ọjọ́ ìsinmi tí ó lọ́wọ̀, ẹ sì gbọdọ̀ gbààwẹ̀. Ọjọ́ ìsinmi náà yóo bẹ̀rẹ̀ láti ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹsan-an títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹwaa.”

33. OLUWA sọ fún Mose

34. pé kí ó sọ fún àwọn eniyan Israẹli pé, “Láti ọjọ́ kẹẹdogun oṣù keje lọ, ẹ óo ṣe àjọ̀dún Àgọ́ fún OLUWA; ọjọ́ meje ni ẹ óo fi ṣe é.

35. Ìpéjọpọ̀ mímọ́ yóo wà ní ọjọ́ kinni, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ líle kankan ní ọjọ́ náà.

36. Ọjọ́ meje ni ẹ óo fi máa rú ẹbọ sísun sí OLUWA. Ní ọjọ́ kẹjọ, ẹ óo ní ìpéjọpọ̀ mímọ́, ẹ óo sì rú ẹbọ sísun sí OLUWA. Ìpéjọpọ̀ tí ó lọ́wọ̀ ni, nítorí náà, ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ líle kankan.

37. “Àwọn àjọ̀dún wọnyi ni OLUWA ti yà sọ́tọ̀; ẹ óo máa kéde wọn gẹ́gẹ́ bí àkókò ìpéjọpọ̀ mímọ́, láti máa rú ẹbọ tí a fi iná sun sí OLUWA, ẹbọ sísun, ati ẹbọ ohun jíjẹ; ati ẹbọ ohun mímu, olukuluku ní ọjọ́ tí a ti yàn fún wọn.

38. Àwọn ẹbọ wọnyi wà lọ́tọ̀ ní tiwọn, yàtọ̀ sí ti àwọn ọjọ́ ìsinmi fún OLUWA, ati àwọn ẹ̀bùn yín, ati àwọn ẹbọ ẹ̀jẹ́ yín, ati àwọn ọrẹ ẹbọ àtinúwá tí ẹ óo máa mú wá fún OLUWA.

39. “Lẹ́yìn tí ẹ bá ti kórè àwọn èso ilẹ̀ yín tán, láti ọjọ́ kẹẹdogun oṣù keje lọ, kí ẹ máa ṣe àjọ àjọ̀dún OLUWA fún ọjọ́ meje; ọjọ́ kinni ati ọjọ́ kẹjọ yóo jẹ́ ọjọ́ ìsinmi tí ó lọ́wọ̀.

Ka pipe ipin Lefitiku 23